Ọlọ́pàá yìnbọn pa Salisu níbi tó ti ń wọ́de ní Kano, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá bá ní kí wọ́n tìí sí gbaga

Aworan ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, other

Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kano lo ti fi panpẹ ọba mu ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa fun ẹsun pe o ṣekupa ọkunrin kan, Salisu Player, leyi to fa rukerudo lagbegbe Kurnar Asabe, nijọba ibilẹ Fagge nipinlẹ naa.

O kere tan, ẹni meji lo fara gbọta nigba tawọn ọlọpaa de sibi gbọnmisi-omioto to n waye lagbegbe naa ti ọkan ninu wọn si padanu ẹmi rẹ nile-iwosan ti wọn gbe e lọ.

Iroyin iku Salisu lo mu ki awọn olugbe agbegbe naa o bẹrẹ ifẹhonuhan leyi to mu ki wọn di oju ọna to wọ ipinlẹ Katsina ati apa kan ipinlẹ Jigawa lati agbegbe wọn

Oju ọna ti wọn di yii ni awọn kan juwe bii ọkan lara awọn naa ti awakọ gba julọ nipinlẹ naa nitori o jẹ ọna abawọle ati abajade kan ṣoṣo si ọpọlọpọ ilu.

Ki lo faa ti awọn ọlọpaa fi lọ agbegbe naa?

Ohun taa gbọ ni pe awọn ẹgbẹ meji n gbena woju ara wọn lori ọrọ obinrin.

Wọn ni obirin ọun ni ọkunrin kan lati ẹgbẹ mejeeji n ba sọ ọrọ ifẹ leyi to da wahala silẹ nigba ti awọn mejeeji mọ sii.

Laasigbo yii ni wọn wi pe o ti bẹrẹ lati ọjọ Aje, leyi to mu ki kọmiṣọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ Kano, Muhammed Gumel, o paṣẹ ki awọn ọlọpaa o lọọ pẹtu si aawọ naa.

“Lojuna ati le awọn to n fa wahala ọhun sẹyin ni awọn ọlọpaa bẹrẹ si nii yinbọn so ke amọ ibọn ba awọn bii meji, ti ọkan lara wọn si baa lọ” gẹgẹ bi oṣojumikoro kan ti ko fẹẹ ki wọn darukọ oun ṣe wi.

“Ẹ lọ fọkan bale, idajọ ododo yoo waye lori ọlọpaa to yinbọn paayan”

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kọmiṣọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Muhammed Gumel, ti wa rọ awọn olugbe ipinlẹ ọhun lati gba alaafia laaye nitori pe oun ti n gbe igbesẹ ti yoo jẹ ki ẹni ti aje iṣẹlẹ naa ṣi mọ lori o lee fimu danrin.

Ninu atẹjade kan latọwọ agbẹnusọ ajọ ọlọpaa nipinlẹ ọhun, Abdullahi Haruna-Kiyawa, o wi pe “lẹyin wakati diẹ, ọwọ ti isipẹkitọ to yinbọn ọhun, o si ti wa ni ihamọ.

“Iwa ti isipẹkitọ yii hu ko dun mọ wa ninu rara nitori ko tii si ede aiyede kankan laarin ọlọpaa ati araalu lati igba ti kọmiṣọna yii ti wọṣẹ, depo pe yoo fa ibọn yinyin.

“Gbogbo aye lo mọ pe ajọ ọlọpaa ipinlẹ yii n bọwọ fun ofin ati awọn araalu. Eyi lo jẹ ki a maa fi daa yin loju pe idajọ ododo yoo waye lori ọrọ yii.

“Kọmiṣọna ajọ ọlọpaa ipinlẹ yii ba mọlẹbi oloogbe kẹdun, o si ṣe adura pe ki Ọlọrun tẹẹ si afẹfẹ rere.

“O waa rọ awọn araalu lati bu omi suuru mu nitori ajọ ọlọpaa ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ ọun.

“A fẹẹ ki ẹ mọ pe asiko to nira fun ajọ ọlọpaa ni yii ati gbogbo olufẹ alaafia nipinlẹ yii, ki a ma jẹ ki awọn janduku o sọọ di iwọde oṣelu ti wọn yoo fi ba nkan jẹ.”