Israel bẹ̀rẹ̀ sí ń sọ àdó olóró sí Gaza lákọ̀tun, ọ̀pọ̀ òkú sùn

Israel war

Oríṣun àwòrán, getty images

Lẹyin ti adehun alaafia ọlọṣe kan pari, Isreal ti bẹrẹ si n sọ ado oloro si Gaza bayii.

Ki ikọlu tuntun yii to bẹrẹ si n waye ni Israel ti n kilọ pe oun yoo bẹrẹ pada.

Israel ni oun ti kọlu agbegbe ti ko fdn ni 200 lati igba to ti bẹrẹ ikọlu naa pada lọjọ ẹti.

Lara awọn to farapa ninu ikọlu yii ni awọn ọmọde wa, ti awọn ile iwosan to ti kuin fọfọ tẹlẹ si n gba awọn alejo tuntun.

Fun igba akọkọ ni Gaza laarin ọsẹ kan, ko si aye lati ko ohun elo iranwọ wọle mọ.

Wayi o, awọn eeyan Gaza ti n bẹbẹ pe ki Israel dawọ ado oloro ọhun duro.

Ṣaaju ni Israel ati Gaza ti kọkọ a naka anbku si arawọn fun didalẹ adehun alaafia ti wọn fọwọ si lori awọn eeyan to wa ni igbekun.

Ẹwẹ, akọwe ijọba ilẹ Amẹrika, Anthony Blinken sọ pe orilẹ-ede oun yoo tẹsiwaju lati maa gbe awọn igbesẹ alaafia, eyii to ti so eso rere fun ọjọ meje.

Amọ ṣa, ẹnikan to sunmọ ijọba ilẹ naa sọpe ijiroro alaafia to n lọ lọwọ ni Qatar ti fori ṣọpọn.

Iroyin ni agbegbe Khan Younis, ni Ghaza Strip, ni ibugbamui alẹ ọjọ Abamẹta ti milẹ titi julọ.