Iléeṣẹ́ ààbò So-Safe lé òṣìṣẹ́ rẹ̀ kan fẹ́sùn olè jíjà

So-Safe

Oríṣun àwòrán, So-Safe

Iléeṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò Social Orientation and Safety Corps, So-Safe ti ìpínlẹ̀ Ogun ti kéde pé àwọn ti lé ọmọ ẹgbẹ́ àwọn kan.

Ẹ̀sùn olè jíjà ni So-Safe fi kan ọmọ ẹgbẹ́ wọn ọ̀hún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adeboye Yusuf Sunday.

Àtẹ̀jáde tí Agbẹnusọ So-Safe, Moruf Yusuf fi léde ni wọ́n ti fi ìkéde náà síta pé ọ̀gá àgbà àjọ náà, Soji Ganzallo ti buwọ́lù ú pé kí wọ́n lé Adeboye Yusuf Sunday kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀hún.

Ó ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni iṣẹ́ Adeboye parí lọ́dọ̀ àwọn látàrí bí ó kópa nínú ìwà olè jíjà kan ní ilé tí wọ́n gbà á sí láti máa ṣọ́ ní agbègbè Onibunkun, Obantoko, Abeokuta.

Ganzallo ní ẹni tó ni ilé tí Adeboye ń ṣọ́ náà ló wá fi ẹ̀sùn kàn pé àwọn nǹkan ìní òun tó wà nílé òun sọnù láàárín ọjọ́ kejìlá sí ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kọkànlá.

Ó ní èyí ló mú kí àwọn ṣe ìwádìí láti fìdí ohun tó bá ṣẹlẹ̀ múlẹ̀ tí àwọn sì fi póró òfin gbé Adeboye lẹ́yìn tó jẹ́wọ́ pé òun mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó fi kun pé Adeboye tún jẹ́wọ́ pé òun tún ti jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan nínú ilé náà.

Ganzallo ní oníbàárà àwọn náà ti gbà láti gba àwọn nǹkan ìní rẹ̀ padà tí Adeboye náà sì ti ní òun máa dá wọn padà.

Ó wá rọ gbogbo àwọn ènìyàn láti yẹra fún bíbá Adeboye Yusuf Sunday ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé iṣẹ́ àwọn nítorí àwọn kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú rẹ̀ mọ́.

Ó ní àwọn ní ìgbàgbọ́ pé ìgbésẹ̀ àwọn yìí yóò kọ́ àwọn mìíràn lọ́gbọ́n láti gbájúmọ́ iṣẹ́ tí àwọn bá gbà wọ́n fún.