Gbogbo àkáǹtì tí kò bá ní NIN tàbí BVN la máa tì pa – CBN

Ile ifowopamo CBN

Oríṣun àwòrán, CBN/X

Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN ti kéde pé ó pọn dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣí akoto owó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú lílo nọ́ḿbà ìdánimọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn NIN tàbí nọ́ḿbà ìdánimọ̀ ti báǹkì ìyẹn BVN tàbí kí wọ́n lo méjéèjì.

Fún ìdí èyí, CBN ní bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹta ọdún 2024, gbogbo akoto owó tí wọn kò bá lo àwọn nọ́ḿbà ìdánimọ̀ yìí ni wọn kò ní rí owó kó síbẹ̀ tàbí gba owó jáde.

Wọ́n ní àwọn akoto owó ni wọ́n gbọdọ̀ so àwọn nọ́ḿbà ìdánimọ̀ yìí pọ̀ mọ́ kó tó di ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kìíní ọdún 2024.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí CBN fi léde lọ́jọ́ Kìíní oṣù Kejìlá ọdún 2023 sí gbogbo àwọn ilé ìfowópamọ́ àtàwọn ilé ìfowópamọ́ kéréje ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ yìí.

CBN ní gbogbo àwọn akoto tó ti so nọ́ḿbà ìdánimọ̀ BVN pọ̀ ni àwọn máa fi sí abẹ́ NIBSS, ICAD lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n bá ṣí akoto owó náà.

Wọ́n ní ìgbésẹ̀ yìí ń wáyé láti jẹ́ kí àwọn ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ owó fẹsẹ̀ múlẹ̀ àti pé kí wọ́n lè nímọ̀ kíkún nípa àwọn oníbàárà wọn.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn akoto owó tó wà ní ipele kejì àti kẹta gbọdọ̀ so NIN àti BVN mọ́ akoto wọn.

Àtẹ̀jáde náà tẹ̀síwájú pé ṣíṣí akoto owó gbọ́dọ̀ jẹ́ gbígba BVN àti NIN ẹni bẹ́ẹ̀ láti NIBSS láti mọ̀ nípa onítọ̀hún.

Wọ́n ní ó pọn dandan fún àwọn iléeṣẹ́ yìí láti tẹ̀lé òfin náà lẹ́yẹ ò sọkà àti pé wọn ò gbọdọ̀ ṣí akoto owó ti ipele àkọ́kọ́ láì lo BVN tàbí NIN.

CBN ní àwọn máa ṣe àyẹ̀wò àwọn akoto owó tó ti wà nílẹ̀ àti pé àwọn máa fi iya tó tọ́ jẹ ilé iṣẹ́ tó bá lòdì sí òfin yìí.