Kí ni ìtumọ̀ ìdókòwò ọ̀tun fáwọn báńkì àti bó ṣe kan oníbàárà wọn?

Aworan banki apapọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Central Bank of Nigeria

Lẹnu lọọlọ yii ijọba aarẹ Bola Tinubu ti n kọ orin ọhun lowe lowe pe ki awọn ile ifowopamọ Naijiria lọ gbaradi daada lati le ṣe ojuṣe wọn ninu eto ọrọ aje ti ijọba fẹ ṣe nipa idagbasoke ọrọ aje Naijiria.

Koko erongba ijọba si ni pe ko jẹ ki ẹka ọrọ aje gbooro debi ti owo ati dukia idokoowo yoo to triliọnu kan dọla tabi ju bẹẹ lọ.

Ipa pataki si ni awọn ile ifowopamọ ni lati ko ti erongba yoo ba di imuṣẹ.

Gẹgẹ bi awọn amugbalẹgbẹ aarẹ ati ọga agba banki apapọ Naijiri a ṣe n sọ, ko ni pẹ ti ijọba yoo fi kede eto idokowo ọtun eyi ti yoo mu ki ẹsẹ awọn ileeṣẹ ikowopamọ duro digbi ti alabara wọn naa yoo si fi jẹ anfaani to pọ.

Fun idi eyi, awọn ile ifowopamọ kan ti n duna dura bi wọn yoo ṣe pawọpọ ki wọn baa le kaju oṣunwọn nipa iye owo ti o wa lakata wọn.

Awọn eyi ti ko fẹsẹ rinlẹ naa la n gbọ pe awọn to duro deede n gbero lati kowo ra wọn ki wọn ma ba ba iji lọ.

Laipẹ yi ni Gomina banki apapọ Naijiria, Olayemi Cardoso sọ pe ijọba apapọ n gbero lati ṣe eto ọrọ aje ti yoo le ni triliọnu dọla kan laarin ọdun meje to n bọ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni ikapa awọn banki ikowopamọ ṣe pataki nitori ki wọn baa le lagbara ṣe iru idokowo ti triliọnu dọla yi yoo mu wa.

Ibi ti ọrọ ti wa fojuhan pe idokowo ọtun yi yoo waye botilẹ jẹ pe wọn ko ti kede gbogbo ilana to so mọ.

Bi wọn ba wa bẹrẹ rẹ, ki ni yoo jẹ ipa rẹ lori awọn alabara nbanki bi emi ati iwọ?

Njẹ igba akọkọ ree ti iru nkan bayi yoo waye ati pe ki lafojusun awọn to fẹ ṣe iru eto yii?

Kini itumọ igbesẹ yi ti banki apapọ Naijiria fẹ gbe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọrọ taa gbọ lẹnu Gomina banki apapọ lori idokowo ọtun yi ni pe awọn igbesẹ kan ti yoo ṣoro lati gbe yoo ba iyipada yi waye.

Lara rẹ si ni pe awọn ile ifowopamọ yoo ni lati mu alekun to lamilaaka ba iye owo ti wọn ni gẹgẹ bi ile ifowopamọ.

Ni ṣoki ati leleyi ti yoo ye awa ara ilu, banki to ba ni bi apẹrẹ biliọnu mẹẹdọgbọn Naira lowo tiẹ to ko jọ, yoo ni lati mu alekun ba owo yi ko ba lee bawọn banki ti ijọba fọwọ si kẹgbẹ.

Re capitalisation ni oloyinbo n pe igbesẹ yi o si jẹ ọna ti wọn yoo fi tun gba owo wọle si fun ileeṣẹ́ ifowopamọ ki wọn baa le fi kaju gbendeke iye owo ti ijọba la kalẹ pe wọn gbọdọ ni

Banki apapọ Naijiria lofin gbaṣẹ le lọwọ lati maa fi odinwọn si iye owo ti banki gbọdọ ni.

Loore koore si ni iyipada maa n ba iye owo yi gẹgẹ bi wọn ba ṣe ri pe o yẹ ki wọn gbe osunwọn yi si.

Owo idokowo banki kọọkan ti bẹrẹ si ni gbera lẹyin ti Gomina banki apapọ kede pe awọn ko ni pe gbe ilana kalẹ fawọn banki lati ṣe afikun owo idokoowo ti wọn ni.

Igba wo ni banki apapọ gbe iru igbeṣe yi kẹyin?

Lọdun 2004 Gomina banki apapọ Charles Soludo ṣe afikun owo idokoowo awọn banki lorileede Naijiria.

O gbe iye oṣunwọn ti wọn gbọdọ ni lọ soke lati biliọnu meji si biliọnu marundinlọgbọn.

Igbesẹ yi mu adinku ba iye banki to wa nilẹ tẹlẹ iyẹn mkandinlaadọrun(89) si mẹrinlelogun(24).

Nigba taa n wi yi, awọn banki kan gba akoso awọn ti ko lalaafia daada ti awọn mii si pawọpọ sọ ara wọn di banki kan ṣoṣo.

Idi ti banki apapọ fi lawọn gbe igbesẹ yi si ni pẹ awọn fẹ ki awọn banki to ba wa lorileede yi fẹsẹ rinlẹ ki wọn si lalaafia lati ṣe owo to peye pẹlu awọn alabara wọn.

Eyi si niigba ikẹyin ti banki apapọ Naijiria ti paṣẹ pe ki wọn ṣe alekun owo idokowo banki lorileede Naijiria.

Naijiria nikan si kọ ni iru nkan bayii ti n waye.

Lorileede America fun apẹrẹ lọdun 1980s wn di iye banki to wa lorileede na ku lati ẹgbẹrun mejila si ẹgbẹrun meje.Ni ọdun 2023 yi, iye awọn banki yi ti walẹ si ẹgbẹrun marun un din diẹ(4,448)

Apapọ iye owo tawọn banki yi ni si le ni triliọnu mẹtalelogun dọla US$23.5tn

Bawo ni igbesẹ yi ṣe kan iwo to ni owo ni banki?

Ọjọgbọn Jemilat Omolara Yaqub, to jẹ olukọ ni ẹka eto ọrọ aje nile ẹkọ giga Fasiti ijọba ipinlẹ Eko, Lagos State University, LASU ni igbesẹ ti ijọba fẹ gbe yii dara pupọ fun ilọsiwaju orilẹ ede.

Ọjọgbọn Yakub ni yoo jẹ ki awọn ile ifowopamọ yii fẹsẹ rinlé daadaa, ti wọn ko si ni maa kogba sile ti nnkan kekere ba ṣẹlẹ si wọn .

O ni eyi yoo mu ki owo awọn onibaara to wa ni akoto awọn ile ifowopamọ yii wa ni aabo to peye nitori wọn ni owo to owo lati fi ṣowo ati pe awọn banki naa ko ni tete maa ku.

"Idi ti ijọba fi ni ki awọn ile ifowopamọ fi kun owo okoowo wọn ni lati ri pe owo awọn to n fi owo si banki ko parun mọ banki."

Ọjọgbọn yii ṣalaye pe igbesẹ yii maa n ṣokunfa ti awọn banki meji tabi mẹta n papọ di ẹyọkan latari a ti wa ni ibamu pẹlu ofin ijọba.

O fi kun pe ti igbesẹ bayii ba n waye, awọn ara ilu nilo lati fi ọkan wọn balẹ, wọn o nilo lati paya tabi maa sa kijokijo lati ko owo wọn kuro nile ifowopamọ wọn.

O ni igbiyanju lati ko owo kuro ni awọn banki yii ni o le ṣakoba fun owo awọn eniyan to si le mu ki banki naa parun.

Bakan naa lo ṣalaye pe ijọba ti gbe awọn ajọ kan dide lati maa ṣamojuto awọn ile ifowopamọ lati mojuto eto bi wọn ṣe n ṣiṣẹ ti owo awọn ara ilu ko fi ni parun si wọn lọwọ.

O ni eyi lo fa idasile awọn ajọ bii Nigeria Deposit Insurance Corporation, NDIC lati maa da aabo bo owo awọn eniyan to ba ni owo lakoto banki.

Ọjọgbọn wa parọwa sawọn ara ilu lati fọkan balẹ pe iru eto bayii ti ṣẹlẹ ṣaaju ti ko si si ohunkohun to ṣẹlẹ si owo awọn eniyan to wa ni awọn banki ti parapọ mọ omiran.