'Àwa ò ní gbà o, àyàfi tí ẹ bá fún wa láǹfàní àti máa ṣẹ́yún'

Àkọlé fídíò, 'Àwa ò ní gbà o, àyàfi tí ẹ bá fún wa láǹfàní àti máa ṣẹ́yún'
Aworan awọn obinrin

Ọrọ oyun ṣiṣẹ ti di eyi ti a n gba bi ẹni n gba igba ọti bayii lorilẹede Kenya pẹlu bi awọn obinrin kan ṣe n ja fun anfani lati lee ṣẹ oyun lai jẹ wi pe ẹgba ofin doju kọ wọn.

Ni orilẹede Kenya, ẹṣẹ nla ni labẹ ofin fun ẹnikẹni lati ṣẹ oyun, ayafi to ba jẹ majeṣin tabi oyun to fẹ gba ẹmi obinrin naa.

Ni bayii awọn obinrin, paapaa awọn ẹgbẹ ajafẹtọ kan lorilẹede naa ti n ja fun ayipada ofin yii eyi ti wọn ni o n da ẹmi awọn obinrin legbodo.

Bakan naa lawọn igun miran n fi aake kọri pe ko si ohun to jọ ọ ati wi pe dada ko daa to ofin yii.