Oṣù kínní ọdún 2024 lètò ẹ̀yáwó fawọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò bẹ̀rẹ̀, Tinubu ṣàlàyé lórí ìṣúná 2024

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe afojusun ijọba oun ni lati ri daju pe iye owo to n wọle sinu apo Naijiria pọ ju iye owo to n jade lọ.
Tinubu fi kun pe ijọba oun ni afojusun ki ọrọ aje Naijiria gbe pẹli si ni ida 3.76% lọdun 2024.
Aarẹ lo sọ ọrọ yii lasiko to n ṣagbekalẹ eto iṣuna ọdun 2024 niwaju awọn aṣofin atawọn aṣojuṣofin niluu Abuja.
Eto iṣuna ọhun lo pe orukọ rẹ ni Ire Ọtun, “Renewed Hope.”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn nnkan to ṣe koko ninu eto iṣuna naa ni aabo orilẹ-ede, ipese iṣẹ labẹle ati mimu adinku ba iṣẹ ati oṣi lawujọ.
O ni “A ni ireti pe ọrọ aje wa yo dagba si ni ida 3.76%, eyii to ju afojusun idagbasoko awọn ọrọ aje orilẹ-ede agbaye lọ.”
Lasiko to n ba awọn aṣofin naa sọrọ, Tinibu sọ pe eto abo ilu jẹ oun logun gidi.
O ni eto iṣuna ọhun pese aye fun idagbasoke ọmọniyan, paapaa awọn ọmọ wẹwẹ.
Aarẹ tun fikun pe ijọba oun ti ṣeto bi wọn yo ṣe ko obitibiti owo si ẹka eto ẹkọ ki awọn ọdọ Naijiria le ni ọjọ iwaju to dara.
Tinubu pari ọrọ rẹ pe ijọba yoo sa ipa rẹ lati san awọn gbese to jẹ ninu 2024.
O ni “Naijiria ni afojusun lati san awọn gbese to jẹ, a n woye pe ida 45% owo ti a ba pa wọle ni a maa fi san gbese.”
Ti ẹ ko ba gbagbe, igba akọkọ ree ti Tinubu yoo ṣagbekalẹ eto iṣuna gẹgẹ bii Aarẹ lẹyin to gori alefa ni nnkan bii oṣu mẹfa sẹyin.
Ààrẹ Tinubu yóò gbé àbá ètò ìṣúná ọdún 2024 síwájú aṣòfin àpapọ̀ l'Ọ́jọ́rú

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Ọjọru ọsẹ ti a wa yii ni Aarẹ Bola Tinubu yoo ṣe agbekalẹ eto iṣuna ọdun 2024.
Ninu atẹjade kan ti Shuaibu Maina Birma buwọlu lorukọ akọwe ile igbimọ aṣojuṣfin lo ti kede bẹẹ lorukọ ijọba apapọ.
Atẹjade naa ni “wọn ti ni ki n kede fun yi pe Aarẹ Naijiria yoo ṣagbekalẹ eto iṣuna ọdun 2024 nibi ipade kan pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba atawọn ọmoo ile igbimọ aṣojuṣofin.”
Ẹwẹ, ijọba apapọ ti buwọlu owo ti iye rẹ to ₦27.5trn fun eto iṣuna ọdun 2024.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ipade kan ti ile naa ṣe, nibi ti wọn ti fẹnuko pe ₦700 ni Naijiria yoo maa parọ fun $1 owo ilẹ Amẹrika kan.

Oríṣun àwòrán, Shuaibu Maina
Awọn aṣofin naa tun fẹnuko pe Naijiria yoo maa ta agba epo bẹntiro kan ni $73.96.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade igbimọ ijọba, minisita fun eto iṣuna, Abubakar Bagudu, sọ pe awọn ti ṣe agbeyẹwo iye owo dọla si naira ati iye owo agba epo bẹntiro kan.
Gẹgẹ bii ohun ti Bagudu sọ, ijọba ijọba ti buwọlu ₦27.5trn gẹgẹ bii eto iṣuna ọdun to n bọ, eyii to fi ₦1.5trn le ju eto iṣuna ọdun yii lọ.
O fi kun pe igbagbọ wa pe owo ti iye rẹ to ₦18.2trn ni ijọba yoo pa wọle lọdun naa, eyii to pọ ju iye owo to pa wọle lọdun to kọja lọ.













