‘Àwọn ọlọ́pàá pa irọ́ ìdigunjalè mọ́ mi, gbé àwòrán mi sórí ayélujára láì ṣe ìwádìí, mo wá di ẹni tí ẹbí ọ̀rẹ́ ń sá fún’

Wọn ni agba adura ni ki a maṣe jọ ẹni ti wọn n wa fun nnkan buruku.
Eyi gan ni o ṣe kongẹ pẹlu iṣẹlẹ to ṣẹ si arakunrin Ṣolankẹ Mutiu ti aworan rẹ jade lori ayelujara lasiko diẹ sẹyin lẹyin ti wọn fi ẹsun idigunjale kan an.
Ọgbẹni Mutiu ṣalaye fun BBC News Yoruba pe oun iṣẹ atọkọṣe-mọkaliiki- ni iṣẹ oun, ti oun si tun maa n fi iṣẹ ọdẹ tii lẹgbẹ ki gbogbo rẹ lee jọ ara wọn.

Awọn ọlọpaa kede orukọ mi gẹgẹ bi ole lai ṣe iwadii – Mutiu Solankẹ
O ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti oun n bọ lati ibi iṣẹ. O ni awọn ọlọdẹ to wa ni ibẹ ni wọn da oun duro ti oun si ṣalaye fun wọn pe ibi iṣẹ loun ti n bọ ti oun si fi iwe idanimọ oun han wọn.
O ni wọn beere pe ibọn ti o wa lọwọ oun ko jọ ibọn ti awọn ọlọdẹ maa n lo. O ni oun si ṣe alaye fun wọn pe nitori wahala awọn adigunjale loun ṣe ge ibọn naa kuru diẹ.
Ọgbẹni Mutiu ni gbogbo alaye oun fun awọn ọlọdẹ naa lo ja si pabo, ti wọn si pe awọn ọlọpaa.
O ni ọjọ mẹta ni oun lo ni agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Arẹgbẹ ki awọn larinlọọdu agbegbe to wa sọ pe oun kii ṣe ole ṣugbọn kaka ki awọn ọlọpaa naa tu u silẹ, ṣe ni wọn tun gbe e lọ si ẹka iwadii ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Eleweran.
Ẹ ni ko yọju si ọfiisi alukoro Ọlọpaa – Ileeṣẹ ọlọpaa

Nigba ti BBC News Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ, Odutọla Ọmọlọla ṣalaye pe oun ko le ranti ni pato iṣẹlẹ naa.
Amọṣa o rọ Ọgbẹni Ṣolankẹ Mutiu lati wa si ọfiisi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa lati wa fi ẹhonu rẹ han ki wọn le gba sinu akọsilẹ ni ibamu pẹlu ilana to yẹ.















