Wọ́n gbé àwọn ìlànà tuntun kalẹ̀ fún Tani Olohun láti bọ́ nínú ẹ̀sùn ìbánilórúkọjẹ́

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/Facebook/BBC
Lonii, ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 ni igbẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ ti gbajumọ ajafẹtọọ awọn oniṣẹṣe, Abdulazeez Adegbola, ti ọpọ mọ si Tani Olohun tun waye ni ile ẹjọ Upper Area, Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.
Eyi ni igbẹjọ akọkọ ti yoo waye lẹyin to kuro ni ahamọ ọgba ẹwọn lẹyin ti wọn gba beeli rẹ.
Ohun ti igbẹjọ oni da le lori ni bi Tani Olohun yoo ṣe bọ ninu ẹsun ti wọn fi kan-an naa patapata ti ko si ni si ẹsun kankan lọrun rẹ mọ.
Nigba to n sọrọ nile ẹjọ, Agbẹjọro Usman Saad Imam to n sojuu Alfa Okutagidi to fẹsun ibanilorukọjẹ kan Tani Ọlọhun ni fidio ẹbẹ to ṣe sita ko tii to lati wọgile ẹjọ rẹ.
Imam ni awọn ilana kan wa ti olujẹjọ naa ni lati tẹle ti onibaara oun fi le wọgile ẹsun to ka si Tani Olohun lọrun.
O ni Tani Olohun ko kan si awọn to fi gbe fidio kan nibi to ti n bẹ awọn jade, pe awọn ko ba ti ṣalaye awọn nnkan ti yoo ṣe fun.
Ninu esi rẹ, agbẹjọro to n duro fun Tani-Ọlọhun, Ọgbeni Ademola Banks sọ pe ohun ti Imam gbekalẹ fun ile ẹjọ jẹ iyalenu fun awọn.
Banks salaye pe awọn mejeeji ti jọ fenuko ṣaaju pe ti Tani Olohun ba gba ominira tan, yoo ṣe fidio sita lati tọrọ aforiji, o si ti ṣe bẹẹ ni kete ti ile ẹjọ gba beeli rẹ.
O ni awọn ilana tuntun to n fi lelẹ yii jẹ iyalẹnu fun oun.

Ki ni awọn nnkan ti Okutagidi ati agbẹjọro rẹ ni ki Tani Olohun ṣe lati bọ ninu ẹjọ ti wọn pe e?
Agbẹjọro Imam ni awọn nnkan mẹrin ni awọn n fẹ latọdọ Tani Olohun ati agbẹjọro rẹ ti ọrọ naa ba maa pari patapata.
- O ni Tani-Ọlọhun gbọdọ tọrọ aforiji eyi to maa tẹ jade ninu iwe iroyin Nigeria (National Daily) meji ọtọọtọ.
- Tani Olohun nilo lati tọ awon mẹrẹẹrin to pe e lẹjọ lọ lati tọrọ aforiji, ti awọn yoo si ya a ni fidio bi o ṣe n ṣe bẹẹ.
- Bakan naa ni o tun ni lati kọ iwe ẹbẹ si ile ẹjọ kọọkan to n jokoo lori ẹjọ rẹ.
- Nipari, o ni agbẹjọro rẹ gbọdọ kọ iwe ẹbẹ si awọn ile ẹjọ wonyi pẹlu.
Lẹyin itakurọsọ awọn agbẹjọro yii, Adajọ Sunday Adeniyi ni ile ẹjọ yoo fun wọn ni anfani lati sọ asọye pọ ki wọn si pinu lori ohun ti wọn ba fẹ ṣe.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹẹdogun, osu Kiini, ọdun 2024.
Alfa Okutagidi ti o jẹ olupẹjọ nigba to n sọrọ lẹyin igbẹjọ naa ni lotitọ ni oun ti gba ẹbẹ Tani-Ọlọhun lori fidio naa ṣugbọn ohun gbogbo ku sọwọ awon agbẹjọro oun nitori awọn lo mọ ohun to tọ lati se labẹ ofin.
‘Tani Ọlọhun’ farahàn nílé ẹjọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó gba béèlì

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun/bbc
Ilumọọka aja fun ẹtọ awọn ẹlẹsin iṣẹṣe, Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si ‘Tani Ọlọhun’ yoo tun farahan ni ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn fi kan an.
Ile ẹjọ Upper Area, ni Ilorin olu ilu ipinlẹ Kwara ni igbẹjọ naa yoo ti waye niwaju Onidajọ Sunday Adeniyi.
Ile ẹjọ yii lo kọkọ gba beeli rẹ ni ọjọ kẹẹdọgbon osu kẹẹrin ọdun yii sugbon ko lee gba ominira lọjọ naa nitori awon ẹsun iyoku to n jejọ rẹ ni awon ile ẹjọ mii.
Ni ọgbọn ọjọ oṣu kẹwaa ni adajọ majisireeti Muhammad Ibrahim fun onisẹse naa ni beeli lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti wọn gbe ka iwajuu rẹ.
Eyi jẹ beeli keji ninu mẹrin to nilo lati gba koto lee gba ominira lahamo ti wọn sọ ọ si.
Sugbọn ni ọjọ kẹrindinlogun, osu kẹwa yii adajọ majisireeti Muhammad Adam gba beeli rẹ fun ẹsun meji, ibanilorukọjẹ ati didana sun Kurani ti wọn fi kan an.
Ati igba yi ni Tani-Ọlọhun ti wa kuro lahamo ọgba ẹwọn ti wọn fi si sugbon ẹjọ si tẹsiwaju.
Igbẹjọ tẹsiwaju lonii, lati mọ boya wọn yoo wọgile ẹjọ ọhun tabi boya yoo si maa jẹjọ lọ.















