Ẹ dáríjìn wá, kùrukùru ló jẹ́ kí bàálù wa tó yẹ kó balè sí Abuja mórílé Asaba-United Nigeria Airlines

Oríṣun àwòrán, United Nigeria Airlines
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu orileede Naijiria kan ti baalu rẹ ṣina gbe awọn ero lọ si ibi ti wọn o lero ti tọr aforinjin lọdọ awọn ero to wa ninu baalu naa.
Ọkọ ofurufu United Nigeria Airlines kan lo gbe awọn ero to n lọ si ilu Abuja lati Eko lo ṣadede kede nigba ti wọn fẹ balẹ pe awọn ti de ilu Abuja.
Nigba ti awọn ero yoo yọju wo ita wọn ri pe Asaba lawọn wa dipo Abuja ti wọn kede pe awọn ti gunlẹ si.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa fi itọrọ aforijin yi sita to si ṣalaye pe kurukuru oju ọjọ lo mu ki awọn ya lọ si Asaba ati pe ẹni to kede pe awọn ti de si Abuja lo ṣi ikede ṣe.
Iṣẹlẹ yi waye lọjọ Aiku tii ṣe ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun yi.
Kete ti ọrọ yi ṣẹlẹ lawọn kan ti n sọ pe o ṣeeṣe ki wọn ṣi ọna tori pe awọn to yẹ ko fi oju ọna han wọn lo dari wọn si ibomiran.
Ọkọ ofurufu naa pada gbera lati Asaba lọ si Abuja ti ileeṣẹ naa si sọ pe awọn awakọ baalu naa mọ si iyipada oju ọna to yẹ ki wọn gba de ibi ti wọn n lọ yi

Oríṣun àwòrán, United Nigeria
Ariwo sọ loju opo ayelujara
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Niṣe ni ọpọ awọn to gbọ iroyin yi bẹrẹ si ni ṣe eemọ pe ba wo ni baalu to yẹ ko gbera lọ si Abuja ṣe gba ọna Asaba lọ.
Loju opo ayelujara kaakiri ibeere yi lo gbẹnu awọn ọmọ Naijiria ti ọpọ si n kesi awọnalaṣe eto irina ofurufu lati ṣe iwadii to peye.
Bawọn kan ṣe n gbarata lori ohun ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi aimọṣẹ ileeṣẹ ofurufu yi lawọn mii n fi ọrọ yi ṣe awada ti wọn si n sọ pe ki awakọ baalu naa wa ṣeṣi gbe awọn to fẹ japa kuro ni Naijiria lọ si ilẹ Gẹẹsi.
Ninu awọn ti iṣẹlẹ yi ko dun mọ ninu ni Anyaora Okeke to ṣe afihan oju opo bi baalu naa ṣe gbera lati Eko lọ si Asaba.
O sọ pe lati ibẹrẹ pẹpẹ to gbera ni baalu yi ko ti morile Abuja rara debi pe yoo ṣẹri pada si ọna Asaba nigba ti wọn sọ pe oju ọjọ ṣe kurukuru.
O sọ pe kani ọrọ ri bẹẹ pe oju ọjọ ṣe kurukuru, ki lo de to fi jẹ baalu ileeṣẹ United Airlines nikan ni wọn dari pe ko l si Asaba ti awọn iyoku ko si ṣẹri pada bi ti wọn.

Oríṣun àwòrán, anyaora.okereke















