Indonesia ti bẹ̀rẹ̀ síí lo epo pupa láti fi wa ọkọ̀ bàlúù

Oríṣun àwòrán, Epo Pupa ati Ọkọ Baluu Indonesia
Fun igba akọkọ, orileede Indonesia ti fi epo pupa rọpo epo to n gbe ọkọ Baluu wọn fo loke, bẹẹ si ni wọn ti ṣe ayẹwo rẹ.
Laipẹ yii ni orileede Indonesia lo epo pupa lati fi gbe ọkọ baluu akero fo, eyi si ni wọn fẹ maa lo dipo kẹrosiini ati epo rọbii ti awọn ọkọ baluu n lo fi fo.
Gẹgẹ bi awọn orileede ti wọn n ṣe epo pupa ni rẹpẹtẹ (biofuels), wọn ti gba wọn lamọran lati bẹrẹ sii lo epo pupa dipo eyi ti wọn n lo tẹlẹ.
Ọkọ baluu Garuda Indonesia to ni nọmba idanmọ Boeing 737-800NG ni wọn kọkọ fi ko ero ti ko din ni ọgọrun-un lati ilu Jakarta si Surakarta lorileede Indonesia.
Alakoso ati oludasile Garuda Indonesia, Irfan Setiaputra nigba to n sọrọ, o ni irin ajo naa le ni ẹẹdẹgbẹta kilomita (550km), ati pe ko din ni maili 342 (342miles).
O ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ba awọn alakoso ileeṣẹ Pertamina, ileeṣẹ to n ri sọrọ ohun agbara (Energy Ministry) ati awọn ti ọrọ kan lati rii pe wọn bẹrẹ sii lo epo pupa yii.
Bẹẹ lo si awọn fẹẹ jokoo papọ sọrọ lati rii pe owo rẹ ko ga awọn ti yoo nilo rẹ lara.
Ileeṣẹ Indonesian Energy Firm PT Pertamina (PERTM.UL) ni wọn ṣe epo pupa to n gbe ọkọ baluu yii.
Ohun ti wọn pe hydro-processed esters and fatty acid (HEFA) ni wọn fi imọ tẹkinọlọji ṣe lara ẹyìn ti wọn lo.
Reuters sọ pe lati bi oṣu kẹjọ ọdun yii si ibẹrẹ oṣu yii ni Garuda ti bẹrẹ sii ṣe ọpọlọpọ ayẹwo debi ayẹwo ọkọ baluu nipa epo ti wọn ṣẹṣẹ ṣe yii, lati fi mọ bi awọn ẹnjiini naa yoo ṣe ṣiṣẹ daadaa si.
Pertamina sọ pe epo ti wọn yọ lara ẹyìn yii ti mu adinku ba afẹfẹ to n wọnu agbegbe ti wọn pese fun-un, eyi ti wọn pe ni ‘atmosphere warming greenhouse gases compared with fossil fuels’.
Awọn orileede to n pese epo pupa wọn wọnyi tun ti bẹrẹ sii sọ pe ki wọn maa lo awọn epo isebẹ ti awọn araalu n lo fun ipese epo ọkọ ofurufuru naa ti wọn pe ni ‘Sustainable Aviation Fuel (SAF)’.
Harris Yahya to jẹ ọkan lara awọn alakoso Energy Ministry sọ pe lilo epo tuntun ti Biofuels yii yoo mu adinku ba ohun ti wọn pe ni greenhouse effect.
Lọdun 2021, Indonesia lo ẹpọ kan naa yii lati ṣe ayẹwo gbigbe ọkọ baluu to jẹ ti ilu wọn Dirgantara Indonesia jet fo, ti ọkọ baluu naa si fo lati ilu Bandung ni West Java si ilu Jakarta.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufuru to jẹ ọkan lara awọn to n lọ afẹfẹ greenhouse julọ ti n wa ọna ti wọn yoo fi mu adinku ba carbon footprint ti wọn n lo tẹlẹ si ohun miran.
Awọn eeyan ti n sọ pe ileeṣẹ naa yoo nilo lita epo ti ko din ni biliọnu 450 SAF ni wọn yoo nilo nigba ti yoo ba fi di ọdun 2050, iyẹn bi epo naa ba le ṣiṣẹ ohun ti wọn n fẹ.
Ṣugbọn ni bayii, awọn orileede kan ti bẹrẹ sii sọrọ lori ipalara ti epo tuntun yii yoo mu ba wọn nigba ti wọn ba bẹrẹ sii ge awọn ọpẹ ẹyin lulẹ, eyi ti wọn pe ni ‘deforestation’.
Ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, European Union ti fẹẹkantẹlẹ gbe igi dina bi wọn ṣe n gbe epo pupa wọle.
Ninu oṣu kẹrin, ọdun 2022, Indonesia ti fi ofin de gbigbe epo pupa wọle si orileede naa lai fi akoko ṣofo.
Ọna epo rọbii miran ti awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu tun wo lati maa lo niyẹn.
Lati bi ogun ọdun le diẹ sẹyin, wọn ni lilo ohun ti wọn pe ni biodiesel, eyi ti wọn gba lati ara oku ẹranko ni UK ti lọ soke.
Iwadii tuntun tun sọ pe lilo rẹ ti lo soke ni ida ogoji lati ọdun 2006.
Pupọ awọn epo yii ni wọn n lo fun mọto ati awọn tirela nla, ṣugbọn ti ijọba UK ati EU n gbiyanju lati rii pe awọn ohun alopati yii jẹ ki ẹka ọkọ ofurufu lọ soke.
Gẹgẹ bu eto ayika ati irinna, ọkọ ofurufu to n lọ lati Paris si New York yoo gbe oku ẹlẹdẹ nlanla ti din diẹ ni ẹgbẹrun mẹsan (8,800), iyẹn to ba jẹ pe epo ti wọn ri lara awọn oku ẹranko wọnyi ni wọn n lo.












