Ọkọ̀ ojú omi tó kó ọgọ́rùn-ún èèyàn rì sínú omi ní Taraba

Aworan iṣẹlẹ ijamba ori omi kan ree

Oríṣun àwòrán, Ijamba ori omi/Google

Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Binnari to wa ni ijọba ibilẹ Karim-Lamido, ipinlẹ Taraba l’opin ọsẹ to kọja yii, nigba ti ọkọ oju omi to ko eeyan ti ko din ni ọgọrun-un ṣubu lojiji.

Gbogbo awọn to wa ninu ọkọ oju omi nla naa la gbọ pe wọn farapa yannayanna lasiko iṣẹlẹ naa.

Ko si ẹnikẹni ninu awọn eeyan naa to wọ aṣọ aabo ori omi ti a mọ si 'Life Jacket' lasiko ijamba naa to waye ni nnkan bi aago mẹta aabọ ọsan ọjọ Satide to kọja, idi ree ti wọn fi farapa.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Ọja ẹja Mayorenero to wa ni ijọba ibilẹ Ardo-Kola ni gbogbo awọn oniṣowo ati ontaja to wa ninu ọkọ oju omi naa ti n bọ, ti wọn si n pada si Binnari, ijọba ibilẹ Karim-Lamido ni Taraba.

Adele alaga ileeṣẹ eto irinna ori omi nipinlẹ naa, Jidda Mayorenero nigba to n sọrọ ṣalaye pe eeyan mẹẹdogun ni wọn ṣi ṣawari wọn lasiko toun n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Jidda Mayorenero sọ pe iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lati rii pe wọn ri awọn yooku naa yọ jade.

Bakan naa, alaga fidihẹ fun ijọba ibilẹ Ardo-Kola, Dalhatu Kawu ninu ọrọ tiẹ sọ pe ajalu nla ni ijamba naa jẹ fun wọn nipinlẹ Taraba.

Bi ẹ ko ba gbagbe, oriṣiriṣi oniruuru iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju mi yii lo ti waye lati bi ọsẹ meloo sẹyin.

Ni ipinlẹ Niger ni ọkọ oju omi to gbe ogoji eeyan ṣubu nipinlẹ Kebbi.

Bakan naa ninu oṣu kẹsan, awọn mẹrindinlọgbọn ni wọn padanu ẹmi wọn nipinlẹ Niger nigba ti awọn mẹẹdogun miran tun padanu ẹmi wọn ninu ijamba ori omi to waye nipinlẹ Adamawa.

Yatọ si awọn ipinlẹ yii, awọn ipinlẹ bii Kwara, Kogi, Niger, Adamawa, Kebbi, Sokoto, ati Kano naa ko gbẹyin ninu ipinlẹ ti ijamba ọkọ ori omi ti fẹmi awọn eeyan ṣofo, ti pupọ wọn si ni aisi aṣọ aabo lo fa ti ọpọ fi ku.