Ọkọ̀ ojú irin méjì kọlu ara wọn ní India, èèyàn mẹ́tàlá kú, 50 farapa yánayàna

two passenger trains collided in India's southern Andhra Pradesh

Oríṣun àwòrán, AFP

O kere tan, eeyan mẹtala lo ti jade laye, nigba ti aadọta mii farapa lẹyin ti ọkọ oju irin meji kọlu ara wọn ni India.

Ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni ogunlọgọ awọn adoola ẹmi lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati yọ awọn eeyan to ha sibẹ.

Awọn oluwadii sọ pe aṣiṣe awọn eeyan lo ṣokunfa ijamba ọhun.

Aṣoju ijọba ilẹ naa, Narendra Modi, ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si awọn mọlẹbi awọn ti ọrọ naa kan ati pe oun ti kan si minisita ileesẹ to n ri si ọrọ ọkọ oju irin lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.

Agbegbe Vizianagaram ni ijamba ọhun ti waye lalẹ ọjọ Aiku.

Iroyin ni ọkọ oju irin mẹta lo n rinrinajo lati Visakhapatnam si Palasa ki meji ninu wọn to kọlu ara wọn ni nnkan bi aago meje alẹ.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ ọkọ oju irin akọkọ duro laarin ọna latari pe ẹru pọ lori ọkan lara awọn waya rẹ nigba ti ọkọ oju irin keji kọlu u lati ẹyin laarin Visakhapatnam si Rayagada.

Ọgunlọgọ awọn ọkọ addola ẹmi ‘ambulance,’ awọn nọọsi, dokita atawọn adoola ẹmi miran ni wọn lọ sibẹ lati maa yọ awọn eeyan ti ọrọ naa kan.

Ọkan lara awọn agbẹnusọ ileeṣẹ ọkọ oju irin naa, Biswajit Sahu, sọ pe awọn ti wọgile irinajo mẹtalelọgbọn to yẹ ko waye lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Orilẹ-ede India lo ni ọkọ oju irin to pọ julọ lagbaye, ti ẹgbẹgbẹrun awọn arinrinajo si maa n gun un.

Ijamba to gbẹmi eeyan mẹtala yii lo n waye lẹyin oṣu diẹ ti ijamba kan gbẹmi eeyan 292 nipinlẹ Odisha.