Ẹ̀sùn ayédèrú ìwé ẹ̀rí tí wọ́n fi kan Tinubu ni kò jẹ́ kí n ṣàtìlẹyìn fun – Ayo Adebajo

Aworan Alagba Ayọ Adebanjo

Oríṣun àwòrán, Ayọ Adebanjo/Google

Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre Naijiria, Alagba Ayọ Adebanjọ ti sọ pe gbogbo igba ni oju maa n gba oun ti lori ọrọ wahala ayederu iwe-ẹri ti wọn fi ẹsun rẹ kan Aarẹ Bọla Tinubu, ti ko si si atunṣe.

Alagba Adebanjọ lo sọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin PUNCH laipẹ yii.

Ninu ifọrọwerọ naa lo ti sọ pe lori ayederu iwe-ẹri yii ati awọn iwa miran loun ko ṣe ṣatilẹyin fun Tinubu lasiko eto idibo to gbe wọle gẹgẹ bi Aarẹ Naijiria.

Adebanjọ sọ pe lara awọn idi pataki toun ko tun ṣe ṣatilẹyin fun Tinubu ni pe ko si iwa otitọ lorilẹede yii nipa ṣiṣe oṣelu awarawa gẹgẹ bi wọn ti n ṣe l’awọn orilẹede to ti ni idagbasoke.

O ni nigba ti awọn jokoo, wọn ṣe ipade lati bẹrẹ ijọba awarawa, ti wọn yoo si maa pin ipo Aarẹ laarin ẹkun to wa ni Naijiria, ṣugbọn niṣe ni ọrọ yi pada lojiji, to si lo n ba oun lọkan jẹ.

Ninu ifọrọwerọ naa ni olori Afẹnifẹre ọhun ti sọ pe Peter Obi nikan lo fi ọrọ idaniloju rẹ sita pe oun yoo ṣe atunṣe si iwe ofin Naijiria, nitori pe eyi ti a n lo lasiko yii ko yẹ fun ilọsiwaju.

O ni “Ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti Tinubu n sọ, ohun to ba ni lọkan jẹ ni.”

“Ṣe ẹ ri ninu ọrọ wahala iwe-ẹri yii, mo ba orilẹede yii kẹdun gidi, paapaa julọ awọn n gbe lẹyin Tinubu, ṣe wọn le fọwọ sọya pẹlu ẹru ti wọn di lee lori. Nipa ọjọ ibi, iwe ẹri ati awọn ẹsun miran wi pe o mọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Ki lo de to fi jẹ pe oun nikan ni. Nigba ti wọn ti ẹ tun wa gbe iwe ẹri kan jade sita, oun ti wọn tun gbe jade gan-an, akoba lo tun ṣe fun un.

“Lakọkọ, o sọ fun gbogbo agbaye pe oun lọ si ibi bayii, bawo lo ṣe le fọwọ rẹ sọya si pe lotitọ ni. Nigba ti mo sọ pe ibi ni mo ti kawe, ti ẹ si sọ pe ẹ fẹ lọ beere nibẹ boya otitọ, ti mo wa n sọ pe ẹ ko gbọdọ lọ.

“Mo mọ iye awọn ti a jọ jade lasiko kan naa. Ṣugbọn ni iru ọrọ yii, o sọ pe iwe ẹri naa ree ti mo gba ni fasiti, nibi ti ọrọ tun wa de duro, wọn tun n gbiyanju lati yi ọrọ naa.

“Wọn ti wa n yi ọrọ si wi pe ṣe o lọ si fasiti abi ko lọ, ṣe nnkan ti wọn beere niyẹn. Awọn meloo ni wọn lọ si fasiti ti wọn pari ẹ, tabi ti ko ṣe daadaa, iyẹn ni wọn n beere.

“O sọ pe o lọ, o si ni iwe ẹri, ṣugbọn to n purọ mọ sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa iwe ẹri naa, ki lo wa fẹẹ ṣe.

“Nnkan to n ba mi lọkan jẹ lorileede yii ree, paapaa julọ awọn to ṣi n gbe lẹyin rẹ lori ibi ti a ba ara wa de yii, wi pe ọkunrin ti a n pe ni Aarẹ wa ni iru iwa abuku bayii.

"Emi ni mo sọ Tinubu di gomina Eko"

Adebanjo tẹsiewaju pe “O n kọ mi lominu, nitori pe o yẹ ki n wa lara awọn to le maa fọwọ sọya wi pe Tinubu ni Aarẹ orileede yii, nitori pe emi ni mo sọ ọ di gomina ipinlẹ Eko.

“Nigba ti ọrọ wahala iwe ẹri yii bẹrẹ, emi ni mo n gbe lẹyin ẹ, ẹ lọ ṣe iwadii naa. Nigba ti Buhari igba yẹn sọ pe ki wọn lọ gbe e ati emi naa, ṣugbọn mo gba ara mi silẹ nitori awọn ẹri ti mo ni nigba naa.

“Ẹgbẹ oṣelu Alliance gbe apoti kaakiri ipinlẹ mẹrindinologoji orileede yii, ipinlẹ mẹfa pere la mu. Ibẹ yẹn kọ ni mo n lọ, ṣugbọn ti mo fẹẹ sọ ni pe o gbọdọ maa ṣe otitọ ninu awọn nnkan to ba n ba wa ṣe.

“Gẹgẹ bi pupọ yin ṣe gbagbọ wi pe Buhari yoo ṣiṣẹ iyanu ka too dibo 2015. NI bayii, ẹ wa n sọ pe iṣakoso rẹ lo buru ju lorileede yii.

“Nigba yẹn, mo nigbagbọ ninu iwe ẹri Tinubu, ṣugbọn nigba ti awọn ẹri kan wa bẹrẹ sii jẹyọ, mo ni lati sun sẹyin, nitori pe mi o mọ otitọ tẹlẹ, to jẹ ki n gbagbọ ninu ohun to sọ.

“Dele Mohmodu wa lara awọn to n gbe Tinubu lẹyin, sugbọn mo ni lati kii wi pe o duro loti otitọ.

“Njẹ a ri olotitọ kan to la fasiti kọja le sọ pe lotitọ lo gba iwe ẹri naa lati fasiti, abi ki ni wọn n sọ?

“O loun lọ si ile-ẹkọ girama, akọkọ niyẹn. O tiẹ kọkọ sọ pe Government College to wa n’Ibadan loun lọ. Igba to ya o tun sọ pe Government College l’Ekoo, eyi ti wọn ko tiẹ tii da silẹ nigba to sọ pe oun lọ sibẹ.

“O mọ igba ti wọn da ile-ẹkọ naa silẹ, o si wa sọ pe ibẹ lo lọ lọdun 1970, ṣe iyẹn ko to fun un lati fọwọ bo oju rẹ?

“Mi o fẹ da si ọrọ yii, ṣugbọn bawo ni yoo ṣe ri ti mo ba wa ni awọn orileede miran, ti wọn wa n sọ pe ki n wo awọn iwe ẹri aarẹ mi ti a ko ti lee fidi rẹ mulẹ.

“Oun to jẹ mi logun julọ ni pe ka maa pin ipo aarẹ kaakiri ẹya to wa lorileede yii gẹgẹ bi wọn ti n ṣe l’awọn orileede to ku lagbaye bii Amẹrika,

“Kin ni idi ti mo ṣe faramọ Obi, a ti fi ẹnu ko wi pe ka maa pin ipo yii bo ti tọ. Nigba to ba kan Ariwa, ka gbe fun wọn; nigba to ba kan Guusu, ka gbe fun wọn, nigba to ba kan Ila Oorun, ka gbe fun wọn.

“Lẹyin iditẹgbajọba, awọn ologun sọ pe ka bẹrẹ ijọba tiwa-n-tiwa, a si bẹrẹ pẹlu Ọbasanjọ, lẹyin rẹ ni Yar ‘Adua, ko to kan Jonathan ati Buhari.

“Buhari ti wa n lọ, ẹ tun sọ pe ko tun wa si Iwọ-Oorun pada, ṣe otitọ ree, ṣe idajọ ododo ree. A ni lati fi ọrọ ṣiro ara wa.

Adebanjo pari ọrọ rẹ pe “Ẹ si wa fẹ ki awọn Biafra dakẹ, ki wọn maa wo yin niran, ohun ti mo n sọ niyẹn. Idi ti mo fi sọ pe ki ẹ lọ ka ipade akọroyin ti ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣe lati ṣatilẹyin fun Obi niyẹn.”