Àwọn ǹǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Àlàbá Lawson tó jáde láyé

Aworan Alaba Lawson

Oríṣun àwòrán, Alaba Lawson/Wikipedia

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Iyalode Alaba Lawson, Iyalode Ẹgba ati ilẹ Yoruba lapapọ ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrin.

Ile rẹ lo ku si lonii ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide.

Diẹ ree lara nnkan ti ẹ ko mọ nipa akikanju obinrin naa to ti ko ipa takuntakun ninu idagbasoke orileede Naijiria.

Taa ni Àlàbá Lawson tó jáde láyé

Ọjọ kejidinlogun, oṣu kinni, ọdun 1951 ni wọn bi Alaba Oluwaṣeun Lawson sinu idile Oloogbe Alagba Emmanuel Abiọna Jiboku ti awọn eeyan mọ si Jiboku Tannatanna.

Alaba Lawson lọ silẹ ẹkọ alakọbẹrẹ St. James African School to wa ni Idi-Apẹ, Abẹokuta laarin ọdun 1957 si ọdun 1962.

Ibẹ lo gba tẹsiwaju lọ sile ẹkọ girama awọn obinrin ti Abeokuta Girls Grammar School, to si ṣetan lọdun 1968.

Lẹyin eyi lo tẹsiwaju lọ si St. Nicholas Montessori Teachers’ Training College to wa ni Prince's Gate, England lọdun 1973 nibi to ti yege pẹlu ipo kinni ninu imọ eto ẹkọ

Oṣiṣẹ ileeṣẹ mọnamọna ti ijọba Naijiria ti a mọ si Electricity Corporation of Nigeria (ECN) ni baba rẹ ko to jade laye, ti iya rẹ si jẹ ọmọ idile Adẹrupọkọ Coker to wa ni Itẹsi niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaba Lawson ni oludasilẹ ọkan lara awọn ile-ẹkọ to gbajugbaja daadaa lorileede Naijiria, Lawson Group of Schools ti wọn da silẹ lọdun 1977.

Alake ilẹ Ẹgba ana, Ọla Oyebade Lipẹde lo fun Alaba Lawson ni ipo Iyalode ilẹ Ẹgba

Alaafin Ọyọ ana, Ọba Lamidi Adeyẹmi lo gbe oye Iyalode ilẹ Yoruba akọkọ fun Alaba Lawson.

Ọdun 1995 ni Alaba Lawson di Aarẹ fun ẹgbẹ Abeokuta Chamber of Commerce, Industry, Mines Agriculture (ABEOCCIMA) lọdun 1995.

Lọdun 2000 ni wọn dibo yan Alaba Lawson gẹgẹ bi Aarẹ ẹgbẹ Ogun Council of Chambers of Commerce, nibi to ti lo ọdun meji gbako, ko to tun di Aarẹ fun Odu’a Chambers of Commerce.

Alaba Lawson ni Aarẹ obinrin akọkọ fun ẹgbẹ Nigerian Association of Chambers of Commerce, Industry, Mines Agriculture (NACCIMA) lorileede Naijiria lọdun 2017.

Yatọ si eyi, Alaba Lawson naa ni Aarẹ obinrin akọkọ fun ẹgbẹ Federation of West African Chambers of Commerce and Industry (FEWACCI).

Lawson ni alaga ana fun igbimọ iṣakoso ile-ẹkọ gbogboniṣe Moshood Abiọla (MAPOLY) to wa nipinlẹ Ogun.

Iyalode Alaba Lawson ni oludasilẹ ẹgbẹ NACCIMA Business Women Group (NAWORG) kaakiri agbaye, bẹẹ lo tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ Institute of Directors (IoD).

O tun wa lara ọmọ ẹgbẹ Lagos Chamber of Commerce and Industry (LCCI), Nigerian – British Chambers of Commerce (NBCC), to si tun jẹ alaga igbimọ iṣakoso Nigerian Quality Infrastructure Forum(NIQIF).

Ọdun 2009 ni Alaba Lawson da banki ẹyawo ti ABESTONE Microfinance Bank silẹ Abẹokuta, pẹlu erongba lati maa ya awọn ọlọja ati olokoowo kekeeke lowo fun okoowo wọn.

Alaba Lawson tun jẹ olori agba fun ẹgbẹ Women In Logistic and Transport (WILAT).

Bi ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ Ogun ṣe fi Alaba Lawson ṣe Mama Isalẹ wọn, bẹẹ naa ni ẹgbẹ awọn obinrin ti wọn n kọ iroyin, iyẹn National Association of Women Journalists (NAWOJ) nipinlẹ Ogun ati Guusu Iwọ Oorun fi ṣe Mama Isalẹ wọn.

Bakan naa lo tun jẹ Mama Isalẹ fun Nigeria Football Supporters Club.

Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi fi aami ẹyẹ Akinkaju-Obinrin Ilẹ Yoruba (Amazon of Yorubaland) da Alaba Lawson lọla

Lawson ni Aarẹ ẹgbẹ egbe awọn lọbalọba lobinrin ti wọn pe ni Pro-Tempore of the Forum of Female Traditional Rulers ni Naijiria.

Ìyálóde ilẹ̀ Yorùbá, Àlàbá Lawson jáde láyé

Aworan Iyalode Alaba Lawson

Oríṣun àwòrán, Alaba Lawson Group of School/Instagram

Iyalode ilẹ Yoruba, Oloye Alaba Oluwaṣeun Lawson, ẹni to tun jẹ Iyalode ilẹ Ẹgba lapapọ ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrin (72).

Akọwe ẹgbẹ Abeokuta Chambers of Commerce and Industry (ABEOCCIMA), AbdulRahman Maku lo fidi iroyin naa mulẹ,

Maku sọ pe oni tii ṣe ọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 ni mama naa dagbere fun aye.

Oloye Alaba Lawson ti jẹ Aarẹ tẹlẹri fun ẹgbẹ ABEOCCIMA ati NACCIMA ko to ku.

Alaba Lawson wa lara igbimọ alakoso ABEOCCIMA n’ipinlẹ Ogun.

Ninu atẹjade ti Maku fi sita, o ni “O ṣeni laanu lati kede ipapoda Aarẹ ana fun ẹgbẹ Nigerian Association of Chambers of Commerce, Industry, Mines, and Agriculture, NACCIMA ati alakoso agba pata fun ABEOCCIMA, Iyalode Alaba Lawson, Iyalode ilẹ Yoruba.

“Ki Ọlọrun tẹ Alaba Lawson si afẹfẹ rere”

Bakan naa ninu atẹjade ti oludamọran pataki lori eto iroyin fun Alaba Lawson, Ọgbẹni Dimeji Kayọde-Adedeji gbe jade lati fidi iroyin ọhun mulẹ.

Kayode-Adedeji jẹ ko di mimọ pe ile ti mama naa n gbe lagbegbe Quarry Road, niuu Abẹokuta lo dakẹ si.

O ni “A padanu mama wa, alaanu wa sọwọ iku ojiji ni ile rẹ to wa niluu Abẹokuta laarọ oni."

“A dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbe aye mama, nitori to lo igbesi aye rẹ daadaa.

“Iyalode wa saye, o ri, o si bori gbogbo ogun, a si mọ pe yoo bẹrẹ sii sinmi ninu alaafia.”