Òbí tí ọmọ rẹ̀ kò bá kàwé yóò fi ẹ̀wọ̀n ọdún kan jura – Ìjọba

Bela bill

Oríṣun àwòrán, EPA

Ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede South Africa ti buwọlu abadofin kan to fun ijọba lagbara lati lati sọ awọn obi si ẹwọn ti ọmọ wọn ko ba kawe.

Labẹ ofin tuntun ọhun ti wọn pe ni ‘Basic Education Laws Amendment (Bela),’ obi ti ọmọ rẹ ba jẹ isansan tabi ti ko si nile ẹkọ le ṣẹwọn ọdun kan gbako.

Ofin Bela yii tun fofin de bi awọn olukọ ṣe maa n na awọn akẹkọọ ni ilu bara nile ẹkọ.

Ofin tuntun yii ni akọkọ iru rẹ ti yoo ni ipa to lagbara julọ lara eto ẹkọ orilẹ-ede naa lati ọdun 1994.

Ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ loilẹ-ede naa, African National Congress (ANC), sọ pe “ofin tuntun yii yoo yi eto ẹkọ wa pada, yoo si yanju awọn ipenija atijọ ati eyii ti a n koju lọwọ.”

Amọ ṣa, ẹgbẹ alatako, Democratic Alliance (DA) bu ẹnu atẹ lu ofin tuntun naa.

DA ni ofin ọhun fun ijọba lagbara to pọju lori eto ẹkọ, eyii ti yoo doju eto ẹkọ bole lọjọ iwaju.

Gẹgẹ bii ohun ti DA sọ, ofin naa yoo gba agbara lọwọ awọn ile ẹkọ, awọn obi ati awujọ, ati pe o kuna lati koju awọn iṣoro pato to n koju eto ẹkọ ilẹ ọhun.

Ṣaaju ki abadofin naa to di ofin ni ẹgbẹ oṣelu naa ti kọkọ tako o, ti o si dunkoko pe oun yoo gbe ijọba lọ sile ẹjọ ti abadofin naa ba le di ofin.

Onimọ kan nipa eto ẹkọ, Mary Metcalf sọ fun ileeṣẹ iroyin SABC News pe o tọ ki awọn obi foju wina ofin ti awọn ọmọ wọn ko ba kawe.

Ẹwẹ, ọpọ eeyan lo gbagbọ pe ijọba South Africa mọọmọ gbe ofin naa kalẹ lati gbogun ti awọn ẹya Afrikaans orilẹ-ede naa ni.