Wo àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré tíátà Yoruba mọ́kànlá tí wọ́n sọ iṣẹ́ Babaláwo di ìrọ̀rùn nínú eré

Lalude/Alapini/Fatomilola/Chatta/

Oríṣun àwòrán, Instagram: Lalude/Alapini/Fatomilola/Chatta/

Oriṣiriṣi ọna ni awọn oṣere tiata maa n gba yọ nidi iṣẹ wọn, paapaa awọn oṣere Yoruba.

Onikalu oṣere ni wọn yan ipa ti wọn n ko laayo, ti awọn ololufẹ wọn si mọ ipa tabi ipo ti oṣere kọọkan le ko to ba di pe ki wọn bọ si oju agbami.

Bi awọn kan ṣe mọ baale ile ṣe lawọn miran mọ bi wọn ṣe n ko ipa olori ẹbi, ti awọn miran si dangajia nibi ka ko ipa Wolii tabi Pasitọ.

Lonii, a ti mu awọn gbajugbaja agba ọjẹ oṣere ti wọn fi iṣẹ tiata sọ iṣẹ babalawo di irọrun.

Awọn wọnyi si ni awọn ololufẹ wọn maa n fẹẹ ri nidi ipa iṣẹ babalawo, iyẹn ninu awọn sinima agbelewo ti ede Yoruba.

Alagba Ganiu Nafiu - Alapini Oosa

Aworan Alapini

Oríṣun àwòrán, Alapini/Instagram

Àkọlé àwòrán, Aworan Alapini Oosa

Pupọ awọn ololufẹ iṣẹ tiata ni wọn ko mọ orukọ Alapini Ooṣa, iyẹn Alagba Ganiu Nafiu.

Orukọ apejẹ rẹ nidii iṣẹ tiata ni wọn mọ, ti wọn si fi n pe e kaakiri.

Ọdun 1977 ni Ganiu Nafiu darapọ mọ iṣẹ tiata yii, to si fi ipa babalawo bẹrẹ nigba naa titi to fi lokiki kaakiri.

Oloogbe Akin Ogungbe to jẹ baba Ṣẹgun Ogungbe ni Alapini Ooṣa kọ iṣẹ labẹ rẹ, ko to di pe o tun lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣere ti Oloogbe Ray Eyiwunmu to jẹ baba Muka Ray ati Murphy Ray.

Bo tilẹ jẹ pe Alapini ba iṣẹ naa nile ni, ti a si le sọ pe iṣẹ ajogunba ni iṣẹ Babalawo to yan laayo nidi iṣẹ tiata nitori pe oniṣegun pọnbele ni mama to bi baba rẹ, ti baba rẹ naa si jẹ oniṣegun.

Kii ṣe ipa babalawo yii nikan ni Alapini fi gbogbo aye rẹ ko nidi iṣẹ tiata, bo ṣe ko ipa olori ẹbi, naa lo ko ipa Pasito, to si tun ti ko ipa baale ile, ati bẹẹbẹẹ lọ, ṣugbọn sibẹ, awọn eeyan nigbagbọ pe ipa babalawo ni ori fi ran an.

Peter Fatomilola

Aworan Peter Fatomilola

Oríṣun àwòrán, Peter Fatomilola/ Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi wọn ba n sọrọ nipa awọn agba onkotan, onkọwe, olukọni, oṣere ori itage ati sinima, Alagba Peter Fatomilola, kii ṣaimọ foloko.

O ti le ni ọgbọn ọdun ti Alagba Peter Fatomilola ti wa nidi iṣẹ tiata pẹlu ipa Babalawo ti a n sọrọ rẹ yii.

Ipa ti Peter Fatomilola nko ni tiẹ yatọ si ti awọn yooku, nitori pe pupọ awọn to yan iṣẹ Babalawo yii laayo ni wọn fi n ṣe buburu, ṣugbọn eyi ti awọn eeyan mọ baba naa mọ julọ ni alawo ire.

Bi awọn ajẹ tabi ẹlẹgbẹ okunkun ba de eeyan mọlẹ, iyẹn ninu sinima, awọn ololufẹ nigbagbọ pe bi Fatomilọla ba wa nibẹ, yoo tu ẹni naa silẹ ni.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun 1946 ni wọn bi Fatomilola sinu mọlẹbi Abraham Fatomilọla niluu Ifisin-Ekiti to wa ni ijọba ibilẹ Ido-Osi, ipinlẹ Ekiti.

Yatọ si pe ọjọgbọn ni, Peter Fatomilola nko ipa Babalawo nidi iṣẹ tiata, baba rẹ naa to ti di oloogbe, Abraham Fatomilola naa jẹ Babalawo ko to ku.

Imọ ati iriri rẹ nidi iṣẹ Baba rẹ lo mu ki oun naa fẹran kiko ipa Babalawo ninu iṣẹ to yan laayọ.

Ọdun 1967 ni Fatomilọla darapọ mọ ẹgbẹ oṣere ‘Olokun Theatre Group’ ti gbajugbaja agba ọjẹ nni, Oloogbe Ọjọgbọn Ola Rotimi da silẹ.

Rasak Ọlayiwọla - Ojopagogo

Aworan Ojopagogo

Oríṣun àwòrán, Ojopagogo/Instagram

Ọdun 1983 ni Rasak Ọlayiwọla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Ojopagogo bẹrẹ iṣẹ tiata ninu ẹgbẹ ‘Ilumokin Theatre Group’ ti Jẹlili Abọdẹrin tọpọ mọ si Baalẹ Larinka da silẹ nigba naa lọhun.

Igba to ya lo lọ darapọ ‘Alao Shorunk Theatre Group’ lọdun 1985 nibi to ti lo ọdun marun-un, ko to di pe oun naa da ẹgbẹ tiata tiẹ silẹ lọdun 1990.

Bi Ojopagogo ṣe n ṣiṣẹ tiata, to si jẹ gbajumọ ni ipa Babalawo naa lo tun n kọrin.

Olayinka Quadri

Aworan Yinka Quadri

Oríṣun àwòrán, Yinka Quadri/Instagram

Ọlayinka Quadri naa tun jẹ ọkan pataki lara awọn to yan iṣẹ Babalawo laayo nidi iṣẹ tiata, bẹe si ree, ko si ipa ti ẹ gbe fun baba naa, ti ko nii ṣe e bi ẹ ṣe fẹ.

Ẹgbẹ 'Afopina Theatre Group' ni Yinka Quadri fi bẹrẹ lọdun 1976 pẹlu ipa Babalawo.

Awọn sinima ti Yinka Quadri ṣe, to fi gba iyi nigba naa ni ‘Kadara Mi’, ‘Ticket to Life’, ati ‘Obinrin Sowanu’.

Tajudeen Oyewọle - Abija

Aworan Abija

Oríṣun àwòrán, Abija/Instagram

‘Abiiiijaaaaa!!!’ Bi awọn ọmọde ba n ṣere nigba naa, lara ohun ti wọn saba maa n fi da aṣa ni orukọ ‘Abija’.

Orukọ Abija rinlẹ kọja ohun ti a le fọwọ bo nidi iṣẹ tiata, paapaa ni ipa Babalawo.

Bi wọn ba si n darukọ awọn to sọ iṣẹ Babalawo di irọrun nidi iṣẹ tiata, ti awọn eeyan n wo awokọṣe rẹ, Abija jẹ ọkan pataki ti ẹnikẹni ko le fọwọ rọ sẹyin.

Tajudeen Oyewọle ni orukọ ti baba ati iya sọ ọ, ṣugbọn iṣẹ tiata lo fun un ni orukọ ti aye fi mọ ọn, iyẹn Abija.

Ninu awọn fiimu Oloogbe Alaaji Yẹkini Ajilẹyẹ ṣe nigba aye rẹ bii ‘Koto Aye’, ‘Koto Ọrun’ ati ‘Ẹran iya Oṣogbo’ ni Abija fi lokiki, to si tun kopa ninu awọn sinima bii ‘Ọmọ Abọrẹ’, ‘Ẹyin Ogongo’, to fi mọ ‘Iyá ojú àgún’, ati awọn miran.

Ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun ni Abija to bẹrẹ iṣẹ tiata ni ọdun 80s.

Abija wa lara awọn Babalawo ti awọn eeyan maa n lọ sa ba ninu sinima fun iranlọwọ lati gba wọn kuro lọwọ oṣo ati ajẹ, tabi oniruuru aisan ati ogun to ba n ba wọn finra nigba igbagbọ ninu agbara to ni.

Fatai Adetayọ - Lalude

Aworan Lalude

Oríṣun àwòrán, Ladude/Instagram

Nnkanbii ọdun diẹ sẹyin ni awọn ṣẹṣẹ mọ pe Fatai Adetayọ ni orukọ ti Lalude n jẹ.

Bi wọn ba si n darukọ awọn to mọ ipa Babalawo kiko dijudiju, ti wọn si fi ara jin tọkantọkan, Lalude jẹ ẹni akọkọ, kii ṣe ti ahesọ.

Bi Lalude ṣe mọ iṣẹ naaa, lo tun jinlẹ daadaa ninu aṣa, iṣe ati ede Yoruba, to si wa lara awọn ti awọn to ṣẹṣẹ n dide bọ nidi iṣẹ tiata maa n lọ ba fun iranwọ.

Ninu ifọrọwerọ kan ti Lalude ṣe laipẹ yii lo ti sọ pe oun ko ni agbara toun ni ninu iṣẹ tiata loju aye, bi ko ṣe pe idaraya lasan loun fi n ṣe.

Bi Lalude ṣe n ṣoogun ika, naa lo tun jẹ Babalawo olugbala, bẹẹ naa lo tun ṣe oogun owo f’awọn eeyan ninu sinima agbelewo.

Kolonka ni sinima ti Lalude ti kopa, ṣugbọn lara rẹ ni ‘Mayegun’, ‘Ibinu Balogun’, ‘Arikuyeri’, ati awọn miran.

Idowu Adenẹkan, Oluwo Atẹfini

Aworan Oluwo Atefini

Oríṣun àwòrán, Idowu Adenekan/Instagram

Sinima agbelewo ‘Ilu Awọn Oku’ to gbajugbaja ni nnkan bi ọdun mẹtala sẹyin lo tubọ gbe orukọ Idowu Adenẹkan to ko ipa Oluwo Atẹfini jade, gẹgẹ bi ipa Babalawo to ko nibẹ.

‘Olokiki Oru’ lo tun jẹ ki okiki Atẹfini tun jade sii lọdun diẹ sẹyin.

Ṣaaju asiko yii Ewi ni Oluwo Atẹfini n ke kaakiri tẹlẹ, to si tun yan iṣẹ ijọba laayo.

Oun naa tun jẹ ọkan pataki lara awọn to mọ bi wọn ṣe n ko ipa Babalawo ninu sinima agbelewo. Ọfọ pipe da lẹnu rẹ bi ẹni pe iṣẹ yii gan an lo yan laayo loju aye.

Ibrahim Chatta

Aworan Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta/Instagram

Bi wọn ba n darukọ awọn ti ina rẹ n jo lọwọlọwọ nide ka ko ipa Babalawo ninu iṣẹ tiata lasiko yii, Ibrahim Chatta yoo wa lara awọn marun-un akọkọ.

Ọdun 2012, ni okiki Chatta jade nigba to kopa ninu sinima ‘Aiyekootọ’ pẹlu awọn bii Muyiwa Ademọla, Fẹmi Adebayọ, Jide Kosọkọ, Wale Akorede, Dele Odule ati Bisi Kọmọlafẹ.

Ilu Bachita to wa ni ijọba ibilẹ Edu, ipinlẹ Kwara ni wọn ti bi Ibrahim Chatta lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun 1970.

Ọpọ fiimu agbelewo ni Chatta ti kopa, to si jẹ pe ko si ipa ti ẹ ni ko ṣe, ti ko nii ṣe ẹ bi ẹ ba fẹ.

Bi tiata ṣe mọ nipa ipa ọmọ ita, lo mọ nipa ole, ọkọ iyawọ, Aafa, Wolii ati Babalawo to tun ṣẹṣẹ bẹrẹ laipẹ yii.

Ọfọ ati Ewi da gidi lẹnu Ibrahim Chatta to mu ki awọn eeyan maa sọ pe nitori ilẹ Tapa to ti wa lo fa a to fi mọ awọn nnkan naa.

Adewale Alebioṣu, Awo Lọjọọ

Aworan Adewale Alebiosu

Oríṣun àwòrán, Adewaler ALebiosu/Instgram

Bi Adewale Alebioṣu ba n pọfọ lọwọ, awọn eeyan maa n ro pe iṣẹ Babalawo lo fi igbesi aye rẹ kọ ni, ati pe iṣẹ naa lo yan laayo ko to darapọ mọ iṣẹ taiata.

Ṣugbọn Alebioṣu,. Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC YROUBA laipẹ yii lo ti ṣalaye awọn ipenija to maa n koju nidi ipa Babalawo to n ko naa.

Alebioṣu ṣalaye ninu ifọrọwerọ naa pe ṣọọṣi loun n lọ, ṣugbọn awọn eeyan maan fi oju Babalawo wo oun nigba toun ba n jade lọ.

Alebioṣu mọ iṣẹ Babalawo jinlẹ ninu iṣẹ tiata, to si maa n wo awọn bii Lalude gẹgẹ bi awokọṣe nidi iṣẹ naa.

Taofeeq Adewale, Digboluja

Aworean Digboluja

Oríṣun àwòrán, Digboluja/Instagram

Lonii, Taofeeq Adewale ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Digboluja ati Alebioṣu ni wọn jọ n figagbaga nidi iṣẹ taiata, paapaa nibi ka ko ipa Babalawo.

Ipa Digboluja ati Alebioṣu si fẹẹ ba ara wọn dọgba, nitori pe awọn mejeeji ni ọfọ pipe dantọ lẹnu wọn bi ẹni pe iṣẹ ajogunba wọn ni.

Digboluja naa ninu ifọrọwerọ to ṣe sẹyin jẹ ko di mimọ pe oun ko ni nnkan ti a n pe oogun, bi ko ṣe pe iṣẹ toun kọ nidi iṣẹ tiata ni Babalawo, toun si mọ ọn daadaa.

Ọlasunkanmi Akanni, Olohuniyọ

Aworan Olohuniyo

Oríṣun àwòrán, Olohuniyo/Instagram

Akanni Olohuniyọ ni ọdọmọkunrin ti ina ogo rẹ tun n jo lọwọlọwọ nidi ka ko ipa Babalawo ninu sinima agbelewo.

Ọdun 2008 ni Olohuniyọ bẹrẹ iṣẹ tiata lẹkunrẹrẹ, to si ti ko ipa ninu awọn sinima agbelewo loriṣiriṣi.

Lara awọn sinima to ti kopa ni Herbalist Rank’, ‘Ajakuta’, ‘Yahoo Babalawo’ ati awọn miran.