Wo bí obìnrin tó di odò ṣe gbé ọdún Awonga kalẹ̀ sí ìlú Shao níbi tí wọ́n ti ń fi ọ̀pọ̀ omidan f'ọ́kọ

Oríṣun àwòrán, BASAMBO/FACEBOOK
Ọdun Shao Awonga jẹ ọdun pataki ni ipinlẹ Kwara, paapaa julọ ni iluu Shao ni ijọba ibilẹ Moro ipinlẹ Osun.
Ọjọ ọdun yii ni wọn ma n fi ogunlọgọ awọn omidan ilu naa fun ọkọ.
Ẹẹkan lọdun lo ma n waye, oni ọjọ Ẹti si ni ayajọ ti ọdun yii n waye.
Gbogbo ilu Shao ti bẹrẹ ajọyọ bayii, awon awọn ọmọ ilu nile, lajo to fi mọ awon alejo jakejado aye si ti de si ilu ọhun lati sajọyọ ọdun Awonga bi wọn ti n ṣee lọdọọdun.
Awọn ọdẹ naa ti wa ni igbaradi lati fi ijo wọn, pẹlu ọta ati ẹtu da awọn eniyan lara ya nigbati ọgọrọ eniyan yoo tu yaya si ori papa isere e idaraya ile iwe ilu ọhun, lati wẹ ninu asa ati ise ilẹ Yoruba.
Bí Ọdún Awonga se bẹ̀rẹ̀ tó sì di ayẹyẹ ọdọọdún
Ọdun Awonga jẹ ọdun to ti wa lati gba iwasẹ to si ni itumo kikun si awọn eniyan.
Gẹgẹ bi itan, ọdun yii bẹrẹ pẹlu obinrin kan ti orukọ rẹ njẹ Awọn, ti o gba ọna ara yọ si ọdẹ kan ti wọn n pe ni, Omo Olarele.
O si sọ fun un pe oun ni o ni odo ti ọdẹ naa ti ma n mu omi ni gbogbo igba to ba lọ sọdẹ.
Awọn jẹ obìnrin ọlọmu kan, o si beere fun ohun kan pere lọwọ ọdẹ naa.
O ni ki o gbe oun lọ si aafin Ọhọrọ iluu Shao akọkọ, Oba Olanibo, o si gba sii lẹnu.
Lẹyin ọpọlọpọ ipade ti Awon se pẹlu Ọhọrọ ati awon ijoye rẹ, o poora pada.
Sugbọn ki o to lọ, o fun wọn ni oogun kan, o si pa a lasẹ wi pe ki wọn sọ ilu naa ni orukọ oun.
Bakan naa, o ni ki wọn ya ọjọ kan sọtọ ninu ọdun fun iranti oun ati lati se igbeyawo fun gbogbo awon ọmọ obinrin to ti to ile ọkọ lọ ni ọjọ kan naa.
Itan tun fi kun un pe, Awon ṣe ileri ibukun fun gbogbo ọmọ ilu ati alejo ti wọn ba tẹle awon ilanaa rẹ.
O sọ wi pe ki wọn maa beere ohun gbogbo ti wọn ba n fẹ ni igbakuugba, papaa julọ, bi ọjọ bayii ti wọn se ọdun Awon.
Lati igba naa ni fífi awọn ọmọbìnrin fun ọkọ lọjọ Ọdun Awonga o si ti di etutu ati ara asa ati ise iluu Shao, ti wọn si n pe ilu naa ni Shao Awonga















