Kí ló mú kí ọ̀gá kan dá àgùnbánirọ̀ kúnlẹ̀, máa nù ú lọ́rọ̀?

Agunbanirọ to kulẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ajọ agunbanirọ lorilẹede Naijiria, (NYSC) ti ni awọn yoo ṣe iwadii fọnran aworan kan to safihan ọkan lara agunbanirọ to n kunlẹ, to ba silẹ bii pe awọn ọga ibudo to ti n sisẹ n ba a wi.

Idi ti omidan naa fi wa lori ikunlẹ ni ko ti ye ọpọlọpọ awọn eeyan.

Sugbọn fọnran ati ohun to wa pẹlu rẹ fihan pe awọn olori ile ẹkọ ti agunbanirọ naa ti n sisẹ n ba wi, to si wa lori ikunlẹ.

Ọrọ miiran to jade ninu fọnran safihan pe awọn Ọga ile ẹkọ n ba agunbanirọ naa wi nitori pe o pẹ de si ibi isẹ.

Ninu alaye agunbanirọ naa, o ni oun ri apẹẹrẹ nnkan oṣu oun, ni oun fi pẹ de si ibi isẹ.

"NYSC ti bẹrẹ iwadii lori fọnran ti agunbanirọ ti n gunlẹ"

Fọnran aworan naa lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lori Ayelujara, ti ọpọ si bu ẹnu atẹ lu isesi awọn adari ile ẹkọ si agunbanirọ.

Nigba to n ba Ileeṣẹ Iroyin abẹle sọrọ, Agbẹnusọ NYSC, Eddy Megwa ni ajọ naa ti bẹrẹ iwadii lori fọnran naa.

“A ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to wayE. Iye ni yoo fun ni anfani lati mọ nnkan to sẹlẹ ni pato.

“N ko le sọ ju bẹlo lasiko yii titi a yoo fi mọ ohun to waye, a ni lati ohun to sokunfa isẹlẹ yii.”