Wọ́n ní kí n wá ṣètò Kola Olawuyi láì dárúkọ́ mi, ọjọ́ kejì ní wọ́n kéde pé ó ti kú - Yemi Odunodu
Odu ni Oba Adeyemi Adebayo Odunodu, kii se aimọ fun oloko nitori akọsẹmọsẹ agbohunsafẹfẹ to dantọ ni.
Koda, se ni awọn eeyan maa n fẹ gbọ awọn eto to ba se, eyi to si gbajugbaja ninu rẹ ni Iriri Aye.
Ki Odunodu, ti ọpọ eeyan mọ si Arole Kola Olawuyi to di ilumọọka, ni eto kan ti wọn n pe ni iriri aye ti wa lori afẹfẹ eyi ti gbajumọ agbohunsafẹfẹ nni, Kolawole Olawuyi n se.
Eto yii si ni Kolawole Olawuyi fi maa n tu asiri awn ohun isẹlẹ to soro gbagbọ eyi to n sẹlẹ nile aye.
Amọ kokoro ko jẹ ka gbadun obi to gbo sasa ni ọrọ iku Kolawole Olawuyi, ọsan kan, oru kan si lo dagbere faye.
Lara eto to si mu ki Olawuyi jẹ aayo awọn ololufẹ rẹ ni eto Iriri Aye to bẹrẹ lori redio FRCN, ko to di pe o fẹyinti lati da duro funra rẹ nileesẹ naa.
Sugbọn nigba ti Olawuyi da duro, o yi orukọ eto naa pada si eto Nnkan Nbẹ.
Ni kete ti Olawuyi si tẹri gbasọ, ni wọn ke si Odunodu lati wa maa se eto naa, ko si tun gba ipo rẹ eyi to mu ki ọpọ eeyan maa pe ni arole Kola Olawuyi.

“Wọ́n ní kí n wá ṣètò Kola Olawuyi láì dárúkọ́ mi, ọjọ́ kejì ní wọ́n kéde pé ó ti kú”
Nigba to n salaye bo se pade Oloogbe Kolawole Olawuyi, Odunodu ni ọjọ pẹ ti Olawuyi ti maa n wo awọn eto ti oun n se lori afẹfẹ lai jẹ ki oun mọ.
O ni igba akọkọ ti oun yoo foju kan Kola, funra rẹ lo ransẹ pe oun, to si mu oun kaakiri awn ibudo igbohunsafẹfẹ rẹ.
“Nigba ti a kọkọ foju kanra wa, o mu mi kaakiri, to si n gbadura pe emi naa yoo ni awọn nnkan ti oun ni.
Igba keji ti wọn pe mi wa sileesẹ rẹ, wọn sọ fun mi pe ki n wa seto Kola Olawuyi amọ n ko gbọdọ darukọ mi.
Wọn ni Kola ko ri baalu wọ wale lati ibi to lọ, amọ ki n seto naa lai fu ara ile lara pe kii se Olawuyi lo n seto naa.
Mo seto naa lootọ, ọjọ keji si ni wọn kede pe Kola Olawuyi ti jade laye, ti ọpọ eeyan si n para poro pe sebi awọn gbọ eto rẹ lana.”
“Ojú mi rí tó lórí ètò Nnkan Nbẹ, àrùn jẹjẹrẹ pa ìyàwó mi, irinṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ N45m jóná”
Nigba to n salaye awọn idojukọ ati ipenija to la kọja tori pe o n tu asiri awọn adiitu ijinlẹ lori eto Nnkan Nbẹ, Odunodu sọrọ, ilẹ kun.
O salaye pe oun ti tojubọ ọpọ nnkan lori eto naa, ti oun si lọ tu awọn nnkan jade.
Odunodu ni ọpọ eeyan maa n ro pe oun se awo ni amọ Musulumi ni oun bi o tilẹ jẹ pe oun kii lọ si Mọsalasi lati kirun nitori oun ko nifẹ lati se ẹgbẹ kankan.
“Ọpọ atako lo pọ fun miigbo ọdaju ni eto Nnkan Nbẹ, kii se ohun ti eeyan lasan le se.
Mo kọ ile kan lati fi se ile iwosan fun iyawo mi amọ se ni aisan jẹjẹrẹ ọyan mu ẹmi rẹ lọ.






