Kókó pàtàkì nípa ẹ̀yáwó akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní 2024

Oríṣun àwòrán, Ile-iṣẹ Aarẹ
Aarẹ Bọla Tinubu ti kede pe eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ Naijiria yoo bẹrẹ ninu oṣu kinni ọdun 2024.
Aarẹ Tinubu kede bẹẹ lọjọ Aje nibi ipade ijiroro eto ọrọ aje Naijiria to waye niluu Abuja.
Bẹẹ ba gbagbe, lara awọn ileri ti Tinubu ṣe lasiko eto ipolongo idibo to gbe e wọle ni eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ yii.
O si buwọ luu gẹgẹ bi ofin fawọn akẹkọọ l’oṣu mẹrin sẹyin.
Nibi ipade ijiroro naa ti aarẹ Tinubu tun ti fi ọkan gbogbo akẹkọọ orileede Naijiria balẹ wi pe iyanṣẹlodi yoo d’ohun igbagbe patapata.
Tinubu ninu ọrọ rẹ sọ pe “nigba ti yoo ba fi di oṣu kin-in-ni, ọdun 2024, eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ.
Fun ọjọ iwaju awọn ọmọ ati akẹkọọ wa ni, mo si tun n sọ pe ko si iyanṣẹlodi mọ.”
Nigba ti aarẹ Tinubu buwọ lu iwe aba eto ẹyawo naa, agbẹnusọ rẹ lori eto iroyin nigba eyi to ti di minisita ohun alumọni inu ilẹ bayii, Dele Alake sọ pe ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ lorileede Naijiria ni yoo maa ṣakoso eto ọhun, ati pe awọn akẹkọọ to ku diẹ kaato fun nile ẹkọ giga nikan ni yoo jẹ anfaani rẹ.
Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa òfin ètò ẹ̀yáwó yìí
Aarẹ ile igbimọ aṣofin kẹsan an to kọja lọ, Fẹmi Gbajabiamila lo gbe aba naa wọ ile igbimọ aṣofin, ti awọn aṣofin fi tẹwọ gba a.
Ofin naa fidi banki eto ẹkọ Naijiria, ti wọn pe ni Nigerian Education Bank kalẹ, eyi ti yoo ni agbara lati “ṣakoso, ṣagbatẹru ati bojuto eto ẹyawo akẹkọọ naa fun Naijiria.”
Awọn akẹkọọ yoo tun ni anfaani lati ya owo yii nipasẹ ile ẹkọ wọn.
Akẹkọọ to ba fẹ ẹ ya owo yii yoo se ayẹwo lati mọ boya o ni awọn amuyẹ to rọ mọ owo yiya naa.
Abala iwe ofin naa ni “ofin lo wa lati pese ọna irọrun fawọn ile-ẹkọ giga fun awọn ọmọ Naijiria nipasẹ eto ẹyawo ti ko ni elelori, lati ipasẹ banki feto ẹkọ Naijiria.”
Ofin tuntun yii lagbara pupọ gẹgẹ bi ofin ti wọn fi da a silẹ, to si fẹsẹ mulẹ gidi, lai ni ohunkohun to le dii lọwọ lati maṣe wa si imuṣẹ.
Lai nii ṣe pẹlu ohun ti ofin miran ba sọ, eeyan le lo ofin naa fun ohunkohun to ba rọ mọ yiya ati bibu ọwọ lu ẹyawo akẹkọọ fun awọn ọmọ ilẹ yii ti wọn ba fẹẹ kawe.
Ko si nnkan to kan ofin yii pẹlu ẹnikẹni to ba fẹẹ lọ kawe niluu oyinbo nitori pe eto ti ijọba orileede yii ṣe fun awọn araalu to fẹẹ ni ilọsiwaju ni Naijiria niyẹn.
Àwọn wo ló ní ànfààní láti yá owó yìí?
Lati ni ẹtọ tabi anfaani si eto ẹyawo yii, o ni lati kọkọ gba iwe ẹri lati kawe ni eyikeyi ile-ẹkọ giga to jẹ tijọba apapọ tabi ti ipinlẹ.
Yala ni yunifasiti, ile-ẹkọ gbogboniṣe, ile-ẹkọ awọn olukọni ti a mọ si kọlẹẹji tabi ile-ẹkọ ẹkọṣẹ ọwọ ti wọn pe ni ‘vocational school’.
Owo to n wọle fun ẹ tabi ti mọlẹbi rẹ ko gbọdọ le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) naira, ki o to le lẹtọ lati gba owoya eto ẹkọ yii.
O nilo oniduro to jẹ oṣiṣẹ ijọba, to si ti lo ọdun mejila gbako lẹnu iṣẹ.
O tun le lo agbẹjọrọ to ti ni iriri ọdun mẹwaa lẹnu iṣẹ, tabi oṣiṣẹ ile-iṣẹ eto ofin yowu.
Èyí ni àwọn ohun tí o tún gbọ́dọ̀ ní láti mọ̀ bóyá o yẹ fún ẹ̀yáwo náà
- Gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn ba fẹ ẹ kawe ni awọn ile-ẹkọ giga to wa ni Naijiria lo koju osunwon
- Awọn akẹkọọ to wa nile-ẹkọ giga aladaani ko si labẹ eto yii
- Ẹyawo yii wa fun gbogbo akẹkọọ ile-ẹjọ giga ti ijọba lai nii ṣe boya ọkunrin niẹ ni tabi obinrin; ẹlẹsin musulumi niẹ ni tabi kristẹẹni
- Ẹya ti o ti wa ko nii nnkan ṣe pẹlu ẹyawo yii
- Boya o ni eyikeyi ipenija ara ko nii nnkan ṣe pẹlu eto ẹyawo yii
- Ofin ẹyawo yii wa fun akẹkọọ to ba fẹẹ san owo ile-ẹkọ giga rẹ
- Iwọ ti o ba n wa owo lati fi si apo, tabi owo lati fi ṣe iṣẹ akanṣe ti ile-ẹkọ tabi nnkan miran, ẹyawo yii ko si fun ọ.
Ẹ̀yáwó yìí kò sí fún ọ bí o bá...
- Bi o ba ti jẹ eyikeyi banki lowo tẹlẹ, ti o ko si tii san an pada
- Bi awọn alakoso ile-ẹkọ ba mu ọ fun ẹsun iwa magomago ninu idanwo, ko saaye fun ọ niyẹn
- Bi ile-ẹjọ ba ti da ọ lẹjọ wi pe o jẹbi iwa aini otitọ tabi ẹsun jibiti
- Bi wọn ba ti mu ẹ fun ẹsun gbigbe egboogi oloro ri tẹlẹ
- Bi baba tabi iya rẹ ba ti kọ lati san owo eto ẹkọ ti wọn ti ya tẹlẹ, o daju pe iwọ o lẹtọọ si ẹyawo yii niyẹn.
Báwo lo ṣe máa san owó yìí padà
- Ẹyawo akẹkọọ yii kii ṣe owo ajọjẹ ijọba ipapọ ti wọn n pe ni ‘national cake’
- Kii ṣe owo ti baba keresimesi n pin lọfẹẹ. O ni lati san an pada
- Ofin naa ti sọ bi ijọba yoo ṣe gba owo wọn pada nigba ti o ba kẹkọọ jade, ti o si ti bẹrẹ sii ri owo tiẹ
- Kii ṣe lati buwọ lu gbigbe owo jade fun awọn to ba yẹ nikan ni ojuṣe banki ẹyawo fun eto yii, bi ko ṣe pe wọn yoo tun maa tọpinpin igba ti akẹkọọ naa ba kẹkọọjade
- Ipin kẹfa ni abala kẹfa ofin naa (Section 6(f)) sọ pe banki naa yoo tun tọpinpin bi ilana eto ẹkọ rẹ ba ṣe n lọ, lati mọ ọdun ti ẹni to ba owo maa kẹkọọ pari, igba ti yoo lọ ṣe agunbanirọ, ati ọdun to ba wọ iṣẹ, lati rii pe wọn gba owo wọn pada lasiko to yẹ
- Wọn yoo tọwọ bọwe adehun pẹlu ẹni to ba gba ẹ si iṣẹ lati rii pe wọn n yọ owo ti o ya diẹdiẹ kuro ninu owo oṣu rẹ titi ti yoo fi pe.
Àwọn ohun mííràn to yẹ ki o mọ niyii...
- Ẹnikẹni to ba gba owo yii gbọdọ san an pada lẹyin ọdun meji to ba pari eto agunbanirọ rẹ
- Ida mẹwaa owo oṣu ti o ba n gba nigba ti o ba ti bẹrẹ iṣẹ ni wọn yoo maa yọ lati ibi ti wọn ba ti gba ẹ si iṣẹ
- To ba jẹ pe iṣẹ adani lo n ṣe lẹyin ti o ba ṣetan, ijọba yoo bẹrẹ sii yọ idamẹwaa ninu gbogbo ere ti o ba n jẹ loṣooṣu
- Iwọ funra rẹ lo maa mu owo naa lọ si banki ẹyawo yii lati san an pada fun wọn
- Ẹnikẹni to ba wa labẹ ofin yii gbọdọ lọ ko gbogbo iwe ẹri ileeṣẹ to da silẹ funra rẹ lọ si banki to ti ya owo naa, to si mọ gbogbo ohun to yẹ lati mọ
- Bi o ba kọ lati san owo naa pada, ofin naa yoo gbe ọ, o si ṣee ṣe ki o fi ẹwọn ọdun meji gbara, tabi ki o san owo itanran idaji miliọnu kan naira; bẹẹ si lo ṣee ṣe ki o ṣẹwọn, ki o tun san owo itanran papọ.















