Àlàyé rèé lórí ohun tó wáyé ní iléẹjọ́ Supreme lórí ẹjọ́ tí Atiku àti Obi pé fi tako Tinubu

Aworan Atiku, Obi ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileẹjọ to ga ju lorilẹede bẹrẹ igbẹjọ ti awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta kan to kopa ninu eto idibo to waye ninu oṣu kei ọdun yii pe ;ati fi tako eto idibo to gbe Aarẹ oriléede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu wọle gẹgẹ bi Aarẹ.

Saaju ni Ileẹjọ to n gbọ awuyeawuye lori eto idibo wọgile ipe awọn ẹgbẹ oṣelu APM, LP ati PDP ti wọn fi tako esi to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bi Aarẹ orilẹede Naijiria.

Igbimọ ẹlẹni meje lo n gbọ igbẹjọ yii, eyi ti Adajọ John Okoro lewaju wọn.

Awọn adajọ yooku ni Uwani Abba-Aji, Lawal Garba, Ibrahim Saulaw, Adamu Janro, Tijjani Abubakr ati Emmanuel Agim.

Chris Uche, SAN to jẹ agbẹjọro fun oludije sipo aarẹ labẹ asia PDP, Atiku Abubakar, ni awọn ẹjọ naa lo ti wa ni ipele pe ki ileẹjọ tẹ ti gbọ wọn.

Uche wa rọ ile ẹjọ lati fun ni anfani lati pese awọn ẹri tuntun to da lori ohun ti wọn gba lati Fasiti Chicago.

Ile ẹjọ wọgile ẹjọ Kotẹmilọrun ti ẹgbẹ oselu APM pe

Bakan naa ni Ileẹjọ Supreme ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement (APM) pe lati fi tako igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima.

Ẹgbẹ ATM lo pe ẹjọ pe kotẹmilọrun pe Shettima ko ni anfani lati dije dupo ninu ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo to kọja.

Igbimọ adajọ ẹlẹni meje kede idajọ yii lẹyin ti agbẹjọro olupẹjọ, Chukwuma Majukwu Umeh, sọ pe oun ko nifẹ lati se ẹjọ naa mọ.

Ki lo sẹlẹ saaju nile ẹjọ Kotẹmilọrun lori ẹjọ ti ẹgbẹ oselu APM pe?

Bẹẹ ba gbagbe, ni alẹ ọjọru, ọjọ Kẹfa, oṣu Kẹsan an ọdun 2023 ni ìgbimọ to n gbọ awuyewuye ìbo aare to waye lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Keji ọdun 2023 gbe idajọ rẹ kalẹ.

Igbìmọ to n gbọ awuyewuye ibo naa ni Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lo jawe olubori níbi eto ìdìbo náa lootọ gẹgẹ bi INEC ṣe kede.

Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Peter Obi ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati ẹgbẹ oṣelú APM lo n pe ijawe oluboro Tinubu lẹjọ niwaju ìgbìmọ to n gbọ ẹhonu ibò.

Wọn ni awọn ni awọn jawe olubori nibi eto ìdìbo to gbe Tinubu wọle ati p ọpọlọpọ kudiẹkudiẹ lo waye lasiko ibo naa