Òkú Gaza di 5,087, ọmọdé 2,055 kú, obìnrin 1,119, arúgbó 217, tí 15,273 sì farapa

Ile ti ado oloro da wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Adnan Elbursh
    • Role, BBC World Service
    • Reporting from, Gaza

Iye awọn eeyan to ba isẹlẹ ikọlu ti orilẹede Israel n se si agbegbe Gaza ti di ẹgbẹrun marun ati ọgọrin le meje (5,087).

Ikede kan ti ileesẹ eto ilera lorilẹede Gaza fisita lo salaye bẹẹ pẹlu afikun pe ni ana nikan, alekun oku ojilerinwo o din mẹrin lo ti kun iye awọn eeyan to ba isẹlẹ naa lọ.

Lara awọn eeyan to ku naa ni awọn ọmọde to to 2,055, 1,119 lo jẹ obinrin, ti 217 si jẹ arugbo.

Bakan naa, awọn eeyan Gaza to to 15,273lo ti fara pa ninu ikọlu ti Israel naa n se si agbegbe Gaza.

Ado iku ni Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idile mi to wa ni Gaza n pin igo omi marun laarin eeyan ọgọrun – Minisita akọkọ nilẹ Scotland

Wayi o, Minisita akọkọ fun Scotland, Humza Yousaf ti salaye pe iya iyawo oun ati ọkọ rẹ lo n la ifiyajẹni nla kọja, bi wọn se ha sinu ikọlu Gaza.

"Se ni awọn to le ni ọgọrun to wa ninu ile kan n pin igo omi marun mu, to fi mọ ọmọ ikoko osu meji.”

"Koda, wọn ko mọ boya awọn yoo ye laarin alẹ kan si omiran nitori ado iku to n fo kiri ni orooru.”

Awọn ana Yousaf lo ha si agbegbe Gaza lasiko ti wọn se abẹwo lọ sibẹ amọ ti wahala bẹrẹ tori ikọlu Hamas si ilẹ Israel.

O wa n rọ ijọba ilẹ UK lati bẹbẹ pe ki wọn si oju ọna Rafah to ja si Egypt silẹ, ki wọn si tun dawọ jiju ado oloro duro.

Aworan araalu kan to n binu lasiko to n kọja ni agbegbe kan ti igugbamu ado oloro ti waye ni Al Zahra

Oríṣun àwòrán, Getty images

"Ìṣẹ́jú márùn-ún ni Israel fi ṣèkìlọ́, kí àdó olóró tó sọ ọ̀pọ̀ ilé wa di èrùpẹ̀"

Ko to diju kala, ile gogoro, Al Zahra to wa ni aarin ilu Gaza di afọkun ile lẹyin ti ado oloro bugbamu ni agbegbe naa.

O to ile gogoro mẹdogun to wo lulẹ nipasẹ ado olor ti Israeli fi ransẹ si Gaza, ti wọn si lepa awọn to nnkan to jẹ oju ni gbese ni agbegbe Gaza.

Obinrin kan to padanu Ile rẹ, Umm Salim aL-Saafin sunkun kikoro bo ṣe sọ fun mi pe awọn ọmọ ologun Israeli pasẹ pe ki wọn kuro ni ile wọn ni ago mẹjọ abọ alẹ ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa.

O tun ni wọn bẹrẹ si ni ma yin ado oloro leralera lati ago mẹsan alẹ wọ ago meje arọ ọjọ keji.

Obinrin di oju rẹ mu, to si sukun lẹyin ti wọn da ile rẹ wo.
Àkọlé àwòrán, Olugbe Al Zahra Umm Salim al-Saafin sọ pe akoko kekere ni wọn fun awọn lẹyin ti wọn ṣe ikilọ, ti wọn si bẹrẹ si ma fi ado oloro ramsẹ.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu Ile rẹ, o salaye pe ilegbe ogun ni ye lo wa nibẹ, ti mọlẹbi kọọkan si wa ni ile kọọkan- to si jẹ pe ko si ẹnikẹni laarin wọn to ni ibi kan lati lọ.

"Araalu ni wa, ti a n gbe igbe alaafia ni ile wa, ki lo de ti ẹ n fi ado oloro ransẹ si wa? Ki ni a ṣe fun iyin" Obinrin mii ti oun naa padanu ile rẹ, Umm Mohammed fẹhonuhan.

Yinyin ado oloro si ile gogoro Al-Zahra ti sọ eeyan to le ni ẹgbẹrun marun un di alai ni ile lori, to jẹ pe ẹgbẹrun eeyan ni Gaza bayii ni ko ni ile lori.

"Ogun ree," eyi ni ọrọ Abu Tami, ọkan lara awọn araalu to padanu ile rẹ.

O ni awọn mọlẹbi kan kọ lati kuro ni ile wọn, to si jẹ pe ile to dawo ti bo wọn mọlẹ. Sugbọn ko ṣeeṣe lati ri oku wọn yọ tabi gbiyanju lati wa awọn to ye nitori awọn eleto ilera ko ni anfani lati de ibi isẹlẹ naa, ti wọn ko si tun ni ẹrọ to yẹ lat se isẹ wọn.

"Gbogbo nnkan ti a ni ti lọ," awọn araalu to pada wa si ile wọn lati wo bi ijamba ṣe sọsẹ ati lati wo boya wọn ma ri awọn dukia to ku sọ fun BBC.

Wọn ko awọn asọ wọn pẹlu asọ ibora, ti wọn kuro pẹlu awọn ibusun wọn.

 Awọn ile gogoro ti wọn dawo lulẹ ni agbegbe Al-Zahra

Oríṣun àwòrán, Getty images

Àkọlé àwòrán, O le ni eeyan 5,000 to padanu ile wọn ninu ikọlu to waye lọjọbọ ọsẹ to kọja.

Sugbọn wiwa awọn dukia to sẹku ni wọn ti daro bayii. Nigba ti BBC si wa ni agbegbe naa, ọkan lara awọn olugbe sọ fun wa pe oun gbe ipe lati ọdọ awọn ileeṣẹ ologun Israeli pe ki awọn kuro ni agbegbe nitori awọn ologun yoo tun wa ba gbogbo awọn nnkan yooku to ku jẹ.

BBC bẹrẹ lọwọ IDF lati sọrọ lori pe ki ni nnkan ti wọn fẹ bajẹ ni agbegbe AL Zahra.

Wọn ni awọn fẹ fesi pada lati tu ileese ologun Hames ati ijọba wọn ka lori ikọlu ti wọn ṣe si Israeli.

"Lati gbe woju Hames lori ikọlu ti wọn ṣe si ọkunrin, obinrin ati ọmọde, IDF n tẹlẹ ofin agbaye, ti wọn si ṣe ojuse lati ko awọn araalu kuro.

 Awọn ile gogoro ti wọn dawo lulẹ ni agbegbe Al-Zahra

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn Ile gogoro yii ni wọn ti kọ lati ọdun 1990s

Ilu AL-Zahra, ni bi ti wọn awọn ile gogoro yii wa, ni wọn kọ lọdun 1990s

Aarẹ Palestinian tẹlẹ, Yesser Arafat pasẹ ki wọn kọ awọn ile gogoro naa lati dena de nnkan ti wọn mọ si itanka Ilu Nitzarim, to wa ni ẹgbẹ ilu naa lati apa ariwa.

Awọn ile gogoro ilu yii ati awọn agbegbe rẹ lo jẹ ti igbalode, pẹlu ile gogoro to le ni ọgọta, ti eeyan le ni ẹgbẹrun mẹwaa si n gbe ni ibẹ. Ile fun awọn osisẹ ijọba, fasiti ati ile ẹkọ ni.

Ile gogoro saaju ikọlu

Oríṣun àwòrán, Al Zahra Municipality

Àkọlé àwòrán, Ile gogoro Al Zahra saaji ikọlu to waye lọjọbọ. Awọn araalu ni agbegbe yii ni ko ki n ṣe ohun ikọlu ninu awọn ogun to saaju.

Hamza, olugbe AL-Zahra sọ fun wa pe ilu naa jina si gbogbo ogun to ti n waye tẹlẹri ati pe ko ki n ṣe ohun ikọlu ninu awọn ogun to waye tẹlẹ. Ero yii lo jẹ ki awọn eeyan sọ ibẹ di ibugbe fun awọn eeyan ti ko ni ile mọ.

Lasiko ti ogun naa bẹrẹ, awọn olugbe AL-Zahra si ilẹkun si awọn mọlẹbi wọn, ti ile kan si ni mọlẹbi meji si mẹta to n gbe ibẹ. nigba ti ikọlu naa waye, ati oni ati alejọ ni wọn ko ni ibi lati duro si mọ.

Koda awọn ti ile wọn ko ti ri ikọlu ko le pada si ile wọn nitori eru pe ikọlu le waye nigba ti wọn ko lero.

Hamza, ẹni to gbe pẹlu awọn mọlẹbi rẹ, sapejuwe isẹlẹ yii gẹgẹ bi ohun to buru gan.

"Ikọlu yii waye lẹyin isẹju marun un ti wọn ṣe ikilọ." o sọ fun wa.