Èèyàn 60 tó gba owóyàá lọ́wọ́ iléeṣẹ́ ayánilówó lórí ayélujára gbẹ̀mí ara wọn
N jẹ ẹ ti ya owo lati ori ẹrọ ayelujara ri lawọn ile ayanilowo to wa lori ayelujara?
N jẹ irufẹ ileesẹ ayanilowo yii ti sẹru ba yin ri tabi ẹbi yin lati sanwo wọn pada?
N jẹ ẹ mọ ẹnikẹni to gbe majele jẹ ri tori pe banki ayanilowo yii dẹru ba a tabi mọlẹbi rẹ?
Ti ẹ ko ba tii ri iru awọn iriri yii ri, ẹ sun mọ ibi lati wa wo ọna tawọn ileesẹ ayanilowo lori ayelujara yii n gba sekupa ọpọ eeyan to ba gba owoya lọwọ wọn lati ori ayelujara.
Ni orilẹede India ni isẹlẹ to ka ni laya yii ti n waye, bi o tilẹ jẹ pe a ri awọn iriri kan naa lorilẹede Naijiria nipa iwa isẹrubani yii.

Ileesẹ ayanilowo n gbe ihooho ati aworan awọn onibara wọn sori ayelujara eyi to gbẹmi eeyan to le ni ọgọta
Ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileesẹ iroyin BBC lorilẹede India lo tanna wadi isẹlẹ yii nibi ti ọpọ eeyan ti fori sọta awọn ileesẹ ayanilowo lori ayelujara naa.
Awọn eeyan to si ti to ọgọta to gba owoya lori ayelujara lo ti gbẹmi ara wọn nitori ojuti ati iwa isẹrubani tawọn ileesẹ ayanilowo naa n ko ba wọn.
Lasiko tawọn eeyan ba fẹ ya owo latori ẹrọ ayelujara naa, se ni awọn ileesẹ ayanilowo naa yoo gba awọn numba ipe to ba wa lori foonu irufẹ onibara bẹẹ silẹ.
Awọn nọmba ipe yii si ni wọn yoo maa fi ọrọ ransẹ si pe ẹbi tabi ọrẹ wn ya owo lọwọ awọn laisan.
Lara awọn iwa adojutini ati asẹrubani mii tawọn ileesẹ ayanilowo naa n hu ni gbigbe aworan ihooho awọn onibara wọn sori ayelujara.
Isẹlẹ si lo maa n waye lasiko tawọn onibara to ya owo lati ori ayelujara naa ko ba tete sanwo naa pada.

Awọn ileesẹ ayanilowo lori ayelujara tun maa n se ẹda aworan onibara ti wọn yoo gbe sori ihoho ẹlomiran lasiko ibalopọ
Koda, awọn ileesẹ ayanilowo lori ayelujara yii tun maa n se ẹda aworan wọn, wọn yoo gbe ori wọn sori ihoho ẹlomiran lasiko ibalopọ, ti wọn yoo si fọn aworan naa sita.
Koda, wọn tun maa n fọn awọn aworan ti ko wu oju ri yii sawọn ẹbi ati ọrẹ awọn onibara bẹẹ, tori pe wọn ni nọmba ipe wọn lọwọ.
Iwa ika yii si ti mu ki ọpọ onibara to gba owoya fi gbe majele jẹ, ti apapọ wọn si ti le ni ọgọta.
BBC tiẹ fimufinlẹ nileesẹ ayanilowo kan lorilẹede India lati mọ bi wọn ti n sisẹ iwa ika wọn.
Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ, ẹ wo fidio yii lati se awari isẹ ibi ti ọpọ ileesẹ ayanilowo lori ayelujara n hu eyi ti wọn fi n da ẹmi ọpọ onibara wọn legbodo.






