Òṣèlú ni igi owó tó ń so jùlọ báyìí ní Nàìjíríà -Afe Babalola SAN

Afe Babalola

Oríṣun àwòrán, others

Odu agbẹjọro to tun jẹ oludasilẹ fasiti Afe Babalola University, nilu Ado Ekiti, ABUAD, Oloye Afe Babalọla, SAN ti ke gbajare pe oṣelu ti di owo aṣepawo bayii lorilẹede Naijiria.

Oloye Afẹ Babalọla salaye nibi ayẹyẹ ikẹkọgboye fasiti ABUAD to waye lọjọ Abanẹta pe ina eto ẹkọ ti n jo ajorẹyin bayii pẹlu bi awọn eeyan ti se wa sọ oṣelu di igi owo lawujọ.

Agba amofin naa ṣalaye pe oun ti ṣe alabapade awọn akẹkọ ti wọn kẹkọ gboye pẹlu maaki to yanranti ni fasiti ti wọn ti kọ jalẹ lati tẹsiwaju eto ẹkọ wọn nigba ti wọn ri ẹni ti ko ni ju iwe ẹri girama to n ri ọwọ họri lagbo oṣelu.

O ni ọpọ awọn ọdọ ti ori wọn ji pepe to yẹ ki wọn jawe gba imọ kun imọ fun idagbasoke orilẹede Naijiria ni wọn ti kọri si oko oselu nigba ti wọn ri awọn ti ko mọọṣe to wọn ti wọn n lami-laaka nitori oselu ṣiṣe.

“Ohun ti orilẹede rẹ sọ Naijiria da niyi.

Okowo kan ṣoṣo to n pawo wọle lorilẹede yii bayii ni oṣelu”