Fún ìgbà díẹ̀ ni ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàíjíríà ń kojú lásìkò yìí – Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti parọwa si gbogbo ọmọ orileede Naijiria lati tubọ fi ara da ipenija ati iṣoro ti wọn n koju lasiko ọwọngogo to wa nita nitori yiyọ owo iranwọ ori epo bẹntiro ti a mọ si sọọbusidi to waye.
O ni fun igba diẹ ni iṣoro naa nitori pe niṣe lọrọ ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii dabi ẹni to fẹẹ jẹ oyin inu apata, ti ko si gbọdọ wo ẹnu aake.
Tinubu sọrọ yii nile ijọba, Aso Rock Villa to wa niluu Abuja, lasiko to n gba alejo ẹgbẹ awọn Musulumi ni guusu iwọ oorun Naijiria.
Nibẹ lo ti sọ pe orileede Naijiria ni lati ru ẹbọ to yẹ, to ba fẹ ilọsiwaju, to si ni lara rẹ ni bi wọn ṣe yọ owo iranwọ ori epo rọbii toun kede lọjọ to gba ọpa aṣẹ gẹgẹ aarẹ Naijiria.
“Nnkan to n koba ọjọ iwaju wa ni. A ni lati ṣe nnkan ti yoo tun ọjọ ọla wa ṣe. Ọlọrun ko le di ẹru ti a ko le gbe ru wa. Ọlọrun ni eto fun wa, eyi lo fa a to fi mu wa wa si ipo ti a wa lonii.
"Nnkan n bajẹ sii lojoojumọ ni, ṣugbọn nipa ifẹ Ọlọrun, nnkan yoo pada rọrun fun wa.
“A ti lo ogoji ọdun laiyọ owo iranwọ ori epo yii. A maa jiya igbesẹ naa bayii, ṣugbọn lati ma ṣe jẹ ki orileede wa doju delẹ, o ṣe dandan lati yọ owo iranwọ naa.
“Ninu itan awọn orileede to ti dagba soke, ohun pataki to mu wọn ni idagbasoke ni bi awọn olori wọn ṣe gbe awọn igbesẹ akikanju lasiko to yẹ fun awọn idi pataki.”
Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe fun igba diẹ ni iṣoro ti orileede yii n koju lasiko yii, to si f’ọkan awọn araalu balẹ pe idunnu ṣi n bọ laipẹ yii.
“A maa gbiyanju agbara wa, eto ọrọ aje wa yoo si ni idagbasoke nitori awọn araalu wa, iyẹn da mi loju, a maa ṣiṣẹ lati rii pe o ri bẹẹ.”
Tinubu pàṣẹ pé kí wọ́n san owó oṣù mẹ́rin fún àwọn òṣìṣẹ́ ASUU

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmẹd Tinubu ti bu ọwọ lu sisan owo oṣu mẹrin fun gbogbo oṣiṣẹ to jẹ ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fasiti Naijiria (ASUU).
Bakan naa lo tun sọ pe oun ti yọ gege ti wọn gbe lori sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ ti wọn da iṣẹ silẹ kuro, eyi to sọ pe ko ni si owo lai si iṣẹ, ti awọn oloyinbo n pe ni ‘No Work, No Pay’.
Ninu atẹjade ti oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin, Ajuri Ngelale gbe jade laipẹ yii lo ti sọ pe lati le mu ileri ti ijọba apapọ ṣe fun ẹgbẹ ASUU ṣẹ, ijọba apapọ ti f’oju aanu wo awọn oṣiṣẹ naa lati tan iṣoro wọn.
Atẹjade naa sọ pe “Lojuna lati mu adinku ba iṣoro ti awọn eeyan n koju ninu igbiyanju lati ṣe atunṣe lori eto ọrọ aje orileede Naijiria, ati lati ṣe otitọ lori iwe adehun ati ajọsọ to waye laarin ẹgbẹ ASUU ati ijọba apapọ Naijiria, Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti paṣẹ pe ki wọn yọ gege to wa lori sisan owo oṣiṣẹ ASUU to da iṣẹ silẹ kuro.
“Eyi yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ASUU to da iṣẹ silẹ tẹlẹ gba owo oṣu mẹrin ninu oṣu mẹjọ wọn, eyi ti a da duro lakoko ti wọn da iṣẹ silẹ fun oṣu mẹjọ.”
Ajuri sọ pe awọn oṣiṣẹ ASUU da iṣẹ silẹ lọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2022, ti wọn si pada sẹnu iṣẹ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2022.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe gege ti wọn yọ kuro yii ni yoo jẹ eyi to gbẹyin ti Aarẹ Tinubu yoo yọ kuro fun awọn oṣiṣẹ ASUU ati awọn ajọ tabi ẹgbẹ oṣiṣẹ miran.












