Ọ̀wọ́ngógó epo ti mú ìnira bá wa, a fẹ́ kí Makinde wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ wa – Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Oyo

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹfẹyinti orilẹede Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ti ke si Gomina Ṣeyi Makinde lati fi o kere tan, ẹgbẹrun lọna ogun Naira kun iye owo ti awọn oṣiṣẹfẹyinti n gba, nitori awọn ipenija ti wọn n koju nipasẹ iyọkuro owo iranwọ epo bẹntiro.
Bakan naa ni wọn pe fun atungbeyẹwo owo oṣu ati itọju awọn oṣiṣẹfẹyinti lasiko ti gbogbo nnkan le koko yii.
Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ipade ti awọn oṣiṣẹfẹyinti ṣe l'Ọjọbọ ni ibudo wọn to n bẹ ni agbegbe Agbarigo, Jericho niluu Ibadan, akọwe ẹgbẹ naa, Olusegun Abatan mẹnuba iredi ti ijọba fi gbudọ wa nnkan ṣe si awọn nnkan ti wọn beere fun.
Abatan ni ipo ti awọn oṣiṣẹfẹyinti ipinlẹ Ọyọ wa tun ti burujai sii nitori iyọkuro owo iranwọ ori epo to waye lai ro tẹlẹ.
Akọwe ẹgbẹ naa ni, "ijọba apapọ ti kede ẹgbẹrun marundinlogoji ati ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn Naira fun oṣiṣẹ ati oṣiṣẹfẹyinti. Ijọba apapọ ko da awọn oṣiṣẹfẹyinti ya sọtọ.
A rọ Gomina Makinde lati gbe igbesẹ kan naa nipa sisan ẹgbẹrun marundinlogoji fun oṣiṣẹ ati ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn Naira fun awọn oṣiṣẹfẹyinti ipinlẹ Ọyọ.
Ẹwẹ, bi iye ti a beere ba pọju lati san, a fẹ ki ijọba ipinlẹ Ọyọ san ẹgbẹrun lọna ọgbọn fun awọn oṣiṣẹ ijọba, ki awọn oṣiṣẹfẹyinti si gba ẹgbẹrun lọna ogun Naira. A ko fẹ ẹgbẹrun mẹwaa Naira rara."
Abatan ni o pọn dandan ki awọn mẹnuba ipa ribiribi ti awọn oṣiṣẹfẹyinti ko ki Makinde to di Gomina fun saa akọkọ ati ikeji.
O ni asiko ti o le san oore fun wọn ni a wa yii, pẹlu alaye wi pe ẹgbẹrun lọna ogun Naira ko pọju. Aṣoju ẹgbẹ naa ni aye yoo tun rọrun sii fun awọn oṣiṣẹfẹyinti bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ba ṣe awọn ohun ti wọn fẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ labẹ aburada 'Nigeria Labour Congress, NLC,' ipinlẹ Ọyọ, Kayode Martins ke si Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde lati yara wa ojutu si gbogbo nnkan ti awọn oṣiṣẹfẹyinti n beere fun gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbesẹ lati mu aye dẹrun fun awọn oṣiṣẹ lẹyin iyọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiro.
Yatọ si nnkan idẹrun ti awọn oṣiṣẹfẹyinti ipinlẹ Ọyọ n beere lọwọ Gomina Makinde, saaju asiko yii ni awọn oṣiṣẹfẹyinti jakejado orilẹede Naijiria ti n foju wina ọkanojọkan ipenija.
Ni ọpọ igba ni a ti gbọ iroyin nipa awọn oṣiṣẹfẹyinti to di alaabọ ara nitori iṣoro to rọ mọ gbigba ẹtọ wọn lọwọ ijọba.
Bi awọn kan ṣe n daku lori ila ni ẹlomii ninu wọn n ku iku aitọjọ.
Eyii lo fa ipe ti awọn oṣiṣẹfẹyinti naa n fi lede lati parọwa si ijọba lori itọju ati awọn ẹtọ wọn.















