Mi ò ṣe wàhálà rárá tí mo fi wọlé ìbò kánsílọ̀ nílùú Igbeti, olóṣèlú Fulani ní Igbeti ṣàlàyé

Yoruba bọ wọn ti ewe ba pẹ lara ọṣẹ yoo pada wa di ọsẹ ni, eyi lo difa fun ọkunFulani kan, Usman Salihu Azeez to jẹ kansilọ niluu Igbeti lapa Oke Ogun nipinlẹ Oyo.
Ọgbẹni Azeez ni iṣẹ ati oko dida tawọn Fulani maa n ṣe ni oun naa n ṣe ṣugbọn oun tun mu oṣelu mọ toun niluu Igbeti.
Azeez ni ‘’ibi bayii ni wọn bi awọn baba wa si niyii, ibi ni wọn bi awa naa si ni Igbeti.
Ti wọn ba bi mi leere pe nibo ni ilu mi, Igbeti naa ni mo maa darukọ tori mi o ni ibo mii ti mo maa darukọ gẹgẹ bi ilu mi.
Awọn baba tiwa fi wa sile iwe, iyẹn lo fun mi ni anfaani lati le darapọ oṣelu.
Lati ibi oṣelu ti mo darapọ mọ yii ni mo ti ni anfaani lati jẹ kansilọ niluu Igbeti.
Emi ni ẹni akọkọ ti yoo jẹ kansilọ ninu ẹbi wa titi to fi di akoko yii.
Mi o ṣe wahala ti mo fi wọle ibo kansilọ niluu Igbeti, ko tiẹ si wahala rara.
Mi o ri ẹya to ko eeyan mọra bi ẹya Yoruba.
Awọn aṣawọ Fulani lo n da wahala silẹ nilẹ Yoruba ti wọn n dẹran jẹko awọn Yoruba.’’






