Iléẹjọ́ tó ga jùlọ yóò bẹ̀rẹ̀ àgbéyẹ̀wò ẹjọ́ tí Atiku pe Tinubu pé kò wọlé ìbò ààrẹ Nàìjíríà

Aworan Atiku ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria yoo bẹrẹ agbeyẹwo ẹjọ ti oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar pe aarẹ Bola Tinubu pe ko wọle ibo aarẹ Naijiria lọjọ Aje ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa yii.

Akọwe ileẹjọ to julọ, Zainab Garba lo fọrọ yii lede ni Ọjọbọ.

Ninu atẹjade to fi sita, Garba sọ pe oun ti ranṣẹ si gbogbo awọn ti ọrọ kan lori igbẹjọ naa gẹgẹ bi ilana to wa ninu iwe ofin Naijiria.

Oludari ọrọ iroyin nile ẹjọ to ga julọ, Ọmọwe Festus Akande naa fidi rẹ mulẹ pe igbẹjọ ọhun yoo bẹrẹ lọjọ Aje.

Ọrọ yii jade lẹyin ti ile igbimọ aṣoju-ṣofin kọnimu lori iṣẹ to pọ fawọn adajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Adajọ mọkanla lo wa nile ẹjọ to julọ lọwọ lọwọ, eleyii to kere si adajọ mọkanlelogun ti iwe ofin Naijiria la kalẹ.

Ile aṣoju-ṣofin tun kepe ijọba apapọ lati gba adajọ sii ki iṣẹ awọn adajọ to wa nibẹ lọwọ lọwọ le dinku.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n foju sọna fun igbẹjọ lori awuyewuye to ṣuyọ lori ibọ aarẹ Naijiria to waye lọjọ keẹdọgbọn oṣu Keji ọdun 2023 yii.