Báwo ni ìjọba Nàìjíríà ṣe yan àwọn tí yóò jàǹfàní owó ìrànwọ́ ₦25,000 fún oṣù mẹ́ta?

Owo naira

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ìjọba àpapọ̀ kéde pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fún ìdílé mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní owó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náírà fún oṣù mẹ́ta.

Ìjọba ní ìgbésẹ̀ náà ń wàyé láti lè mú àdínkù bá ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú látàrí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí ìjọba yọ nínú oṣù Kẹfà ọdún yìí.

Wọ́n ní àpapọ̀ owó náà yóò jẹ́ bílíọ̀nù kan àbọ̀ dọ́là àti pé àwọn àkúṣẹ̀ẹ́ paraku ni owó náà tọ́ sí.

Ní oṣù Kẹwàá ni fífún àwọn ìdílé ní owó náà yóò bẹ̀rẹ̀ tí yóò sì wá sópin ní oṣù Kejìlá ọdún 2023.

Ìbéèrè tí àwọn ènìyàn ń bèèrè ni pé kí ní yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn náà lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí oṣù mẹ́ta tí ìjọba fẹ́ fi fún wón ní owó náà bá pé.

Olùyànnàná ọ̀rọ̀ kan, tó tún olùkọ́ ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fástì ìpínlẹ̀ Kwara, KWASU, Ọ̀mọ̀wé Sulyman Hafees Tosin ní ìgbésẹ̀ ìjọba dàbí ẹni pé wọn kò mọ ohun tó kàn ni.

Ọ̀mọ̀wé Sulyman ní àpapọ̀ owó tí ìjọba fẹ́ fún àwọn akùṣẹ́ paraku yìí kò ju ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́rin náírà fún gbogbo oṣù mẹ́ta yìí ní èyí tí kò ká nǹkankan nínú ìṣẹ́ àti òṣì tó ń bá àwọn ènìyàn fínra.

Ìjọba Nàìjíríà kò ní àkọ́ọ́lẹ̀ orúkọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tó yanrantí, àìmọ ohun tó kàn ni ìgbésẹ̀ láti máa fún àwọn ìdílé ni ₦25,000 fún oṣù mẹ́ta

“Ṣé èròńgbà ìjọba ni láti kàn fara dẹ àwọn ènìyàn fún ọ̀sẹ̀ kan nínú oṣù mẹ́ta yìí ni àbí láti yọ wọ́n kúrò nínú ìṣẹ́ àti òṣì?” ó béèrè

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó ní ohun tó yẹ kí ìjọba ṣe ni láti wá ọ̀nà láti yọ àwọn ènìyàn tó wà nínú ìṣẹ́ kúrò nínú òṣì tó ń báwọn fínra kí ọrọ̀ ajé Nàìjíríà lè tẹ̀síwájú.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ pé àìní àròjinlẹ̀ lórí ètò yìí ni látọwọ́ ìjọba kò dára tó nítorí ìgbésẹ̀ tí wọ́n ń gbé yìí kò ní àǹfàní kankan tí yóò mú bá ìlú.

Ó tẹ̀síwájú pé Nàìjíríà kò ní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn tó ń gbé nínú rẹ̀ tó múnádóko àti pé kò dájú pé àwọn tí ìjọba ní àwọn fẹ́ fún ní owó náà ni yóò rí owó náà gbà.

“Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ní ẹ̀tọ́ sí owó yìí ni wọ́n máa fún, ó kàn dàbí pé ìjọba fẹ́ yín àgbàdo sẹ́yìn apẹ̀rẹ̀ tàbí da omi sínú òkun ni.”

Ọ̀mọ̀wé Sulyman bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésẹ̀ tó tọ̀nà ni bí ìjọba ṣe fẹ́ wá ìdẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn lórí ìnira tí wọ́n kó àwọn ènìyàn sí látara àwọn ètò tí wọ́n gbé kalẹ̀ bí ìṣèjọba yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ àmọ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbé ètò wọn gbà kò dára tó.

Ó ní ìgbésẹ̀ tí ìjọba fẹ́ lò yìí ni ìjọba tó ṣaájú náà lò àmọ́ tí kò so èso rere kankan fún ará ìlú.

“A ò rí àbájáde ire irú ètò yìí lásìkò ìjọba tí ó kọjá, bíi pé ènìyàn kàn ń yín àgbàdo sẹ́yìn apẹ̀rẹ̀ ni nítorí náà kò sí ìdánilójú pé ó máa so èso rere báyìí.”

Gbogbo ìgbìyànjú wa láti bá aṣojú ìjọba sọ̀rọ̀ láti ọ̀nà tí wọ́n gbà fi mú àwọn ìdílé tó máa gba owó náà ló já sí pàbó.

Ìjọba ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò pínpín ₦25,000 fún ìdílé mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún ní Nàìjíríà

Ààrẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Tinubu/FACEBOOK

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti ní ètò pínpín owó bílíọ̀nù kan àbọ̀ dọ́là sí àwọn ìdílé mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.

Wọ́n ní àwọn ènìyàn tí ìṣẹ́ àti òṣì ń bá fínra ni owó náà wà fún láti mú àdínkù bá ọ̀wọ́n gógó tó bá àwọn nǹkan lọ́jà látàrí ìrànwọ́ epo tí ìjọba yọ láti oṣù Karùn-ún ọdún 2023.

Mínísítà fétò ìbójú-àánú-woni àti pípa òṣì rẹ́, Betta Edu ní àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ fún ní owó náà ló jẹ́ mílíọ̀nù méjìlélọ́gọ́ta àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Edu ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náírà ni ìdílé kọ̀ọ̀kan yóò gbà fún oṣù mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹwàá títí di oṣù Kejìlá ọdún yìí.

Ní oṣù Keje ni ìjọba ti kọ́kọ́ kéde pé àwọn ohun ìrànwọ́ tó fi mọ́ pínpín ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà fún àwọn aláìní àmọ́ tí wọ́n ṣe àtúngbéyẹ̀wò rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn figbe ta pé owó náà kéré púpọ̀.

Ní ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹwàá, ní àyájọ́ òmìnira ni Tinubu ti kéde pé àwọn ti ṣe àtúngbéyẹ̀wò owó náà àti pé àwọn tí kò rí ọwọ́ họrí nláwùjọ ni owó náà fún.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde àjọ tó ń rí sí òǹkà àwọn nǹkan ní Nàìjíríà ìyẹn National Bureau of Statistics, (NBS) ní ìdá mẹ́tàlélọ́gọ́ta àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ń gbé nínú ìṣẹ́ àti òṣì.

Mínísítà náà tún ní láìpẹ́ yìí ni àwọn yóò tún gbé ètò mìíràn kalẹ̀ láti pèsè ètò ẹ̀yáwó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà àwọn ọlọ́jà kéréje.

Bákan náà ló ní àwọn máa pèsè àwọn nǹkan tó máa ń mú èrè oko gbèrú si fún àwọn àgbẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ sáà oko gbíngbìn.

Edu fi kun pé àwọn máa ṣètò àyẹ̀wò tí yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn tó ní ẹ̀tọ́ sí owó náà ló gbà á.