Iléẹjọ́ pàṣẹ kí agbófinró mú igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀rí l'Ondo lórí ẹ̀sùn 'jíjí' ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́

Agboola Ajayi

Oríṣun àwòrán, facebook/Agboola alfred ajayi

Ile ẹjọ majisireeti kan nilu Akure to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo lo ti paṣẹ ki awọn ọlọpaa o fi panpẹ ọba mu igbakeji gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Agboola Ajayi, lori ẹsun lilẹdi apopọ lu jibiti.

Majisreeti agba, Taiwo Lebi, lo paṣẹ ki awọn ọlọpaa o fa Agboola wa si iwaju ilẹ ẹjọ naa ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun yi.

Agboola, to jẹ igbakeji fun gomina Oluwarotimi Akeredolu laarin ọdun 2016 si 2020, ni wọn fi ẹsun kan pe o ran awọn meji kan lati fi jibiti gba ọkọ Toyota Camry XLE tuntun ti owo rẹ jẹ miliọnu marun o le ẹgbẹrun lọna irinwo naira (₦5,400,000) lati ọdun 2018.

Afẹsunkanni fun ajọ ọlọpaa lori ẹjọ naa, Emmanuel Tanimowo sọ fun ile ẹjọ pe Agboola Ajayi lakoko to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo ninu oṣu karun ọdun 2018 ran Akintoye Olatunji ẹni ọdun mẹrinlelogoji ati Ogunmusi Samuel ẹni ọdun mejilelaadọta lati lọ fi ọgbọn alumọkọrọyi gba ọkọ tuntun to jẹ Toyota Camry dudu lọwọ Segun Adetuwo.

Agboola Ajayi ati Gomina Akeredolu lasiko ti Ajayi si wa ni ipo igbakeji gomina Ondo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Agboola alfred ajayi

Emmanuel wi pe iwa ti awọn afẹsunkan mẹtẹẹta naa wu lo lodi si ofin orilẹ-ede Naijiria.

Awọn afẹsunkan kini ati ikeji, Akintoye Olatunji ati Ogunmusi Samuel lo ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn nitori pe iṣẹ ti Agboola ran awọn ni awọn jẹ.

Eyi lo mu ki ile ẹjọ o paa laṣẹ pe ki igbakeji gomina tẹlẹri naa o farahan niwaju ile ẹjọ naa lati waa wi tẹnu rẹ.

Alágbára méjì ló n fi oníìbárà mi tayò

Agboola Ajayi ati iwe ifisun rẹ

Oríṣun àwòrán, Agboola Alfred Ajayi/ bbc

Ẹwẹ, agbẹjọro fun ẹni afẹsunkan kini (Akintoye Olatunji), Omolegbon Odusola, ṣe alaye fun ile ẹjọ pe aawọ to waye laarin igbakeji gomina tẹlẹri, Agboola Ajayi ati Segun Adetuwo lo gbe oniibara oun de ile ẹjọ.

Omolegbon wi pe ọrọ ilẹ kan lo fa ariyanjiyan laarin Agboola ati Adetuwo to mu ki Adetuwo o gbe onibara oun wa si ile ẹjọ lojuna ati wọ Agboola sita.

Agbẹjọro fun olupẹjọ (Adetuwo), Alex Olademehin, lakoko to n fesi si ọrọ Omolegbon wi pe ẹjọ to wa nilẹ yii ko nii ṣe pẹlu aawọ dukia to wa laarin onibara oun ati igbakeji gomina tẹlẹri naa.

Olademehin wi pe “oniṣowo pọmbele ni onibara mi to si jẹ pe ọwọ awọn ile ifowopamọ lo ti n yawo lati fi ṣowo.

“Bawo ni ẹnikan ṣe le gba ọkọ to le ni miliọnu marun naira lati bi ọdun marun sẹyin ti ko si gbiyanju lati san kọbọ ninu owo naa?”

Majisreeti Taiwo Lebi waa sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun yi pẹlu aṣe pe ki akọọlẹ ipa ti Agboola Ajayi ko ninu ọrọ naa o wa niwaju ile ẹjọ ti oun funra rẹ ko ba nii si nile ẹjọ.