Ọjọ́ mánigbàgbé ni òru ọjọ́ tí DSS ṣe ìkọlù sílé Sunday Igboho n’Ibadan - Lady K ṣàlàyé

Aworan Lady K ati Sunday Igboho
Àkọlé fídíò, Ọjọ́ mánigbàgbé ni òru ọjọ́ tí DSS ṣe ìkọlù sílé Sunday Igboho n’Ibadan - Lady ṣàlàyé

Lẹyin ọdun meji tawọn oṣiṣẹ ajọ DSS atawọn sọja ṣe ikọlu si ile ajijagbara nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho niluu Ibadan, Oluwakemi Ife-Oluwa Oladele ti ọpọ mọ si Lady K ṣalaye fun BBC ohun to ṣẹlẹ gan an loru ọjọ naa.

Lady K ni ‘’ọjọ ti o lagbara tii ṣe ọjọ kinni oṣu Keje ọdun 2021 ni ọjọ naa.

Ni deede aago kan abọ oru ni mo ṣadeedee gbọ iro ibọn nitori mo wa nile Oloye Igboho niluu Ibadan nigba naa.

Lẹyin naa ni mo rii pe ijọba lo ran awọn DSS ati sọja lati wa mu Igboho.

Nigba to wọn de, ṣe wọn o tiẹ kan geeti, sẹ ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn.n DSS ko ṣẹ lori aye mi.

Iro ibọn yii pọ, o kọja bẹẹ, ibẹru mu mi debi pe mi o mọ ohun ti mo fẹ ṣe mọ.

Lẹyin naa ni mo pinnu lati jẹ ki gbogbo aye mọ ohun to n ṣẹlẹ nile Sunday Igboho gẹgẹ bii iṣẹ mi eyi tii ṣe iṣẹ sọrọsọrọ lori afẹfẹ.

Ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ori bami ko baba mi Ooṣa yọ loru ọjọ naa, baba lọ amọ o ṣeni laanu pe ẹmi eeyan meji lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Lẹyin naa ni wọn mu emi atawọn mọkanla mii ti wọn si ko wa lọ si Abuja nibi ti mo ti lo oṣu mẹrin gbako lahamọọ.

Nibẹ ni mo ti lọ bawọn jẹ ẹwa ko jina.

Iya pọ ninu ahamọ ajọ DSS, wọn lu mi niluu bo ba le o ku koo ku.

Titi di ti mo ṣe n sọrọ yii, mi o pe mọ pẹlu iya ti DSS fi jẹ mi ni ahamọ.

Ki n to de ilu Abuja ni wọn ti bẹrẹ si ni fiya jẹ mi pe mo lori laya gbe awọn sori afẹfẹ.

Ajọ DSS ṣe ayẹwo lori ika mi lati mọ bo ya mo maa n yinbọn.

Ọdọọdun ni mo maa ṣe iranti ọjọ naa nitori ọjọ nla lo jẹ fun mi, ọjọ manigbagbe ni.

Nitori pe Ọlọrun ko jẹ ki n ku, erongba awọn DSS ko ṣẹ lori aye mi.''