Iléẹjọ́ ju ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n ká orí èèyàn mọ́ lọ́wọ́ s'ẹ́wọ̀n ọgọ́ta ọdún

Oríṣun àwòrán, Others
Ileẹjọ Magistrate to n joko niluu Tunga, Minna nipinlẹ Niger tí palasẹ fun ọkunrin marun un ti wọn ká ori eeyan mọ lọwọ lọ ọgọta ọdun lọgba ẹwọn pẹlu isẹ ase kara.
Awọn afurasi naa yoo lo ọdun mejila lọgba ẹwọn fun ẹsun pe wọn fẹ fi ori eeyan naa se ogun owo.
Adajọ Fati Umar Hassan lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Aje, to si ni awọn afurasi naa jẹ bi ẹsun mẹta tí wọn ka sí wọn lẹsẹ.
Awọn afurasi naa ni, Ibrahim Jiya, Suleman Usman, Abdullah Usman, Idris Mohammed ati Isah Mohammed lo wa lati abule Sakpe ni ijọba ibilẹ Edati nipinlẹ Niger.
Olupẹjọ fun ileeṣẹ Ọlọpaa, Mua'azu Abdullahi ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa ni agbegbe Bida lẹyin ti wọn fi ẹjọ naa to ileeṣẹ Ọlọpaa leti.
O sọ fun ileẹjọ pe ninu apo sakasaka ni wọn gbe ori naa si, ti wọn sí jẹ wọ pe babalawo kan lo kí wọn wa orí eeyan wa lati fi se ogun owo lati le ni owo.
"Wọn lọ hu oku ni itẹ oku ti wọn si gbe orí ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Yan Ndako Daniya, ẹni to jade laye lọdun mẹta sẹyin, lasiko ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ Ọlọpaa, awọn afurasi naa jẹ wọ ẹsẹ wọn.
Lẹyin gbogbo atotonu, Adajọ Hajiya Hassan ran ẹni kọkan lọ sẹwọn ọdun mejila pẹlu isẹ ase kara.












