Ta ni Ola Olukoyede, pásítọ̀ ìjọ RCCG tó di alága EFCC?

Oríṣun àwòrán, Others
Alaga tuntun fun ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria., EFCC,, Olanipekun Olukoyede jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti.
Oun ni ẹni akọkọ ti yoo jẹ alaga ajọ naa lati apa guusu orilẹede Naijiria.
Ikere Ekiti ni wọn ti bi Olukoyede si lọjọ Kẹrinla Oṣu kẹwaa ọdun 1969.
Bakan naa lo tun jẹ Pasitọ fun ijọ Redeemed Christian Church of God
O lọ si ile ẹkọ fasiti ipinlẹ Eko LASU, Fasiti ilu Eko UNILAG, Ile Ẹkọ ti àwọn amofin niluu Paris, lorilẹede France ati Fasiti Havard lorilẹede Amẹrika.
Yatọ si pe o n sisẹ pẹlu Ajọ EFCC, Olukoyede jẹ agbẹjọro to ni oye ati iriri ọdun mẹtalelogun lori iwa jẹgudujẹra.
Lọdun 2018, ni wọn yan an si ipo olori osisẹ sni ọfiisi alaga EFCC nigba naa, ki o to di akọwe si ajọ naa ni ilana pẹlu abala keji ofin to ṣẹda ajọ EFCC ti ọdun 2004.
Awọn alaga to jẹ tẹlẹ saaju Ola Olukoyede ni
Mallam Nuhu Ribadu. AIG (rtd.) Alaga lati ọdun 2003-2007.
Farida Waziri. AIG (rtd.) Alaga lati ọdun 2008-2011.
Ibrahim Lamorde. DIG (rtd.) Alaga lati ọdun, 2012-2015.
Abdul Rasheed Bawa, Alaga lati ọdun 2021-2023.
Ààrẹ Bola Tinubu yan alága tuntun fún àjọ EFCC

Oríṣun àwòrán, presidency Nigeria
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti yan alaga tuntun fun ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria.
Ọla Olukoede ni alaga tuntun fun ajọ EFCC bayii lẹyin ti wọn yọ alaga tẹlẹ nibẹ....
Agbẹnusọ fun aarẹ, Ajuri Ngelale ṣalaye ninu atẹjade kan to jade l’Ọjọbọ pe aarẹ orilẹede Naijiria yan alaga tuntun fun ajọ EFCC ni ibamu pẹlu abala keji ofin to da ajọ EFCC silẹ (EFCC act 2004).
O ni saa ọdun mẹrin rẹ yoo bẹrẹ ni kete ti ile aṣofin agba Naijiria ba ti buwọlu iyansipo rẹ.
Ngelale ni aarẹ Tinubu tun yan Muhammad Hassan Hammajoda gẹgẹ bi akọwe ajọ EFCC kan naa fun saa ọlọdun marun un eyi ti yoo bẹrẹ ni kete ti ile aṣofin agba ba ti buwọlu iyansipo tirẹ naa.
“Aarẹ Bọla Tinubu wa gba awọn adari tuntun fun ajọ EFCC naa lamọran pe ki wọn ṣe iṣẹtakun fun igbẹkẹle ti wọn ni ninu wọn lati gba iṣẹ ilu pataki naa fun itẹsiwaju ipinnu tuntun lati tubọ tẹmpẹlẹmọ gbigbogun ti iwa ajẹbanu gẹgẹbi ara opomulero ilepa ijọba aarẹ.”












