Mo ti pàdánù Mohbad, ẹ má jẹ̀ ẹ́ kí n fojú sunkún ọmọ mi - Ìyá Primeboy pariwo síta

Aworan Mohbad ati Primeboy

Oríṣun àwòrán, Others

Iya Ibrahim Owodunni, ti ọpọ mọ si Prime boy, to jẹ ọrẹ timọtimọ fun olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, Mohbad tí pariwo sita pe ki awọn ọmọ Naijiria ran oun lọwọ lẹyin ti ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ọmọ rẹ mole pe o jẹ ọkan lara awọn afurasi lori iku Mohbad .

Lẹyin iwadii, Ileeṣẹ Ọlọpaa kede Primeboy ati ọpọlọpọ afurasi mii bi Nọọsi alabẹrẹ, Feyisoya Ogedengbe, Sam Larry ati Naira Marley, ti wọn si ti wa ni ahamọ Ọlọpaa bayii.

Ninu fọnran kan to wa lori ayelujara, Iya Primeboy kesi awọn ajafẹtọ ọmọniyan ati ọmọ orilẹede Naijiria lapapọ pe ki wọn da si ọrọ naa nitori oun ko fẹ foju sunkun ọmọ.

O sapejuwe Primeboy gẹgẹ onirẹlẹ ọmọ ati pe oun ko bímọ to le ṣekupa eeyan.

"Gbogbo ọmọ Naijiria mo n kesi yín, ẹ jade sí mi

"Ile re ni mo ti wa, nítorí rẹ ni mo fi kọ awọn ọmọ mi daada

"Gbogbo abiyamọ, ẹ dìde simi, Primeboy ni akọbi ọmọ mi, n ko fẹ foju sunkun ọmọ.

"Ko si apayan ni ìran mi, ibanujẹ ọkan lọ jẹ fun emi ati Ibrahim lori Iku Mohbad.

O tẹsiwaju pe bi ọmọ ni Mohbad jẹ si oun ati pe o gbe pẹlu mọlębi oun lasiko to si wa ni Ikorodu

"Mohbad gbe pẹlu wa, oun ati ọmọ mi jẹ ọrẹ timọtimọ.

"Mohbad ti a sọrọ rẹ yii gbe pẹlu emi ati awọn ọmọ mi. Ẹ wa si adugbo wa, ní gbogbo igba ni a jọ ma fi wa papọ.

"Mohbad lo san owo níbi ti mo ti n taja.

"Wọn ti fi Mohbad pami lẹkun, ẹ maa jẹ ki wọn gba Ibrahim lọwọ mi."