‘Ọkùnrin tó fún mi ní ẹ̀bùn N200 ló pariwo pé mo ti mú nǹkan ọmọkùnrin òun’

Aworan awọn ọdọ kan ti wọn n wọde

Oríṣun àwòrán, others

Arabinrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Rahab Emmanuel ti wọn fi ẹsun kan pe o ji nnkan omokunrin eeyan kan gbe lagbegbe Gasa lopopona Airport road nilu Qbuja ti bọ si ojutaye lati ṣalaye pe oun ti oun ati ile oun yoo jẹ loun wa lọ lọjọ a ki o to ku diẹ ki oun pade ohun ti yoo jẹ oun.

Arabinrin Rahab Emmanuel to bi ọmọ mẹrin ṣalaye lori bi o ṣe ku diẹ ki awọn ọdọ adugbo dana sun oun lori ẹsun pe oun ṣe afọwọra nnkan ọmọkunrin arakunrin kan ti oun ri lagbegbe naa.

Arabinrin naa ṣalaye fun kọmiṣọna ajọ gbohun-gbaroye araalu (Public Complaints Commission, PCC) nilu Abuja, Ezekiel Musa Dalhatu to bẹẹ wo ni ile rẹ.

O ni aladugbo kan lo gbe iṣẹ agbafọ fun oun. Ile rẹ loun si n lọ ti oun fi pade arakunrin kan to duro si ibi ṣobu itaja kan nibẹ.

Iṣẹ alagbafọ ti mo gba ni mo n lọ ṣe ti arakunrin kan fi pariwo pe mo ji nnkan ọmọkunrin oun - Rahab Emmanuel

O ni arakunrin naa lo fun oun ni igba naira pe ki oun fi ra ipapanu bisikiti fun ọmọ oun ti oun gbe dani to n sunkun.

“Bi mo ṣe tẹsiwaju si ile arabinrin to gbe iṣẹ agbafọ fun mi naa, arakunrin yii n tẹle mi,lo ba si lọgu lojiji pe mo ti ṣe nnkankan si oun ati wi pe nnkan ọmọkunrin oun ko ṣiṣẹ mọ. Mo sọ fun un pe mi o mọ nnkankan nipa ẹ.”

Nigba ti awọn ọdọ adugbo gbọ ni wọn ya bo ọfiisi awọn fijilante ti mo lọ fi ẹjọ ọrọ naa sun.

“wọn de mi tọwọ tẹsẹ, wọn si lu mi daadaa. Wọn tun gba ẹrọ ibanisọrọ mi nigba ti mo fẹ pe ọkọ mi.”

O ni awọn aladugbo to da oun mọ ni wọn pe ọkọ oun, ẹni to fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ki wọn to wa gba oun silẹ.

Ninu ọrọ rẹ kọmiṣọna ajọ gbohun-gbaroye araalu (Public Complaints Commission, PCC) nilu Abuja, Ezekiel Musa Dalhatu rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadi wọn de oju ami lori iṣẹlẹ naa lati rii pe idajọ ododo farahan fun arabinrin naa.