Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ọba tàbí ìlú tí wọ́n ti jí ọ̀pá àṣẹ tábí adé lọ?

Aworan ade ati opa ase

Kayeefi ni o si n jẹ fun ọpọ eeyan wi pe awọn janduku kan ji gbe ọpa aṣẹ ati ade ọba ilu Ogunmakin ni ijọba ibilẹ Obafemi-Owode, nipinlẹ Ogun lọ.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti ṣe awari ade ọba ilu naa, wọn si n wa ọpa aṣẹ ọba ilu naa.

BBC Yoruba ti beere lọwọ awọn agba nilẹ Yoruba ohun to le ṣẹlẹ ti ade tabi ọpa aṣẹ ọba ba di awati nilẹ Yoruba.

Alagba Peter Fatomilola sọ pe, to ba jẹ pe laye àtijọ́ ni, gbogbo ilu yoo sọ pe ki ọba naa wa a lọ nitori pe kii ṣe oun lo ni i, fun gbogbo ọba to ba jẹ ni.

"Wọn si tun le ṣe etutu lati mu ki ẹni to ji ọ̀pá da a pada tabi ki ọ̀pá àṣẹ fi ẹsẹ ara rẹ rin wa."

Oloye Elebuibon ni ti ẹ sọ pe, ẹni to lọ ọ gbe ọ̀pá àṣẹ ọba ni isalẹ Eko "ti fi ara rẹ ṣepe lai mọ".

Fatomilola ní 'Ọ̀gbẹ́ni' lásán ni ọba tí kò rí ọ̀pá àṣẹ rẹ̀.

O ṣalaye pe etutu ni wọn o ṣe lati ri ọ̀pá àṣẹ naa, ati lẹyin ti wọn ba da a pada tan, ki gbogbo nkan le tuba, ko le tu ṣẹ.

"Awọn to ji ọ̀pá àṣẹ ọba fi tabuku ọba naa ni.

Wọn fẹ ki ọba naa wa lai ni àṣẹ, ọ̀wọ̀ ati agbara.

Oun naa si gbọdọ gbe gbogbo igbesẹ lati da awọn nkan naa pada."

Fatomilola fikun pe, Peter Fatomilola ní 'Ọ̀gbẹ́ni' lásán ni ọba tí kò rí ọ̀pá àṣẹ rẹ̀’ nitori ko ni asẹ lẹnu mọ.

Njẹ awọn janduku ti gbe ọ̀pá àṣẹ ọba ri nilẹ Yoruba?

Oloye Yemi Elebuibon sọ pe, o ti ṣẹlẹ ri, àmọ́ kii ṣe lati ọwọ awọn janduku.

O ni o ma a n ṣẹlẹ, paapa ti wọn ba fẹ ẹ sọ agbara iru ọba bẹ ẹ di yẹpẹrẹ, nitori pe o kọ lati ṣe awọn nkan to yẹ ko ṣe, boya ìrúbọ tabi nkan míì, tabi to ba n ṣe aigbọran.

Sugbọn kii ṣe bi i ki awọn janduku rọ́ wọ aafin.

Oloye Yemi Elebuibon sọ pe, o ti ṣẹlẹ ri, àmọ́ kii ṣe lati ọwọ awọn janduku.

O ni o ma a n ṣẹlẹ, paapa ti wọn ba fẹ ẹ sọ agbara iru ọba bẹ ẹ di yẹpẹrẹ, nitori pe o kọ lati ṣe awọn nkan to yẹ ko ṣe, boya ìrúbọ tabi nkan míì, tabi to ba n ṣe aigbọran.

Sugbọn kii ṣe bi i ki awọn janduku rọ́ wọ aafin.

Èèwọ̀! Àwọn olè ṣọṣẹ́ ní ààfin ọba l'Ogun, wọ́n jí adé àti ọ̀pá àṣẹ lọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kayeefi nla ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun nigba ti awọn afurasi ole kan yabo aafin Olu ti ilu Ogunmakin ni ijọba ibilẹ Obafemi-Owode, Ọba James Sodiya ti wọn si ji ade àti ọpa aṣẹ ọba naa lọ.

Ohun ti a gbọ ni pe ni Ọjọbọ to lọ ni awọn janduku naa wọ aafin ọba ilu naa eleyii to waja ni bii oṣu meji sẹyin.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.

Odutayo ko ṣai sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi mẹta tó níí pẹlu iṣẹlẹ ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa to ṣe apejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi eewọ, fidi rẹ mulẹ pe awọn ti ṣe awari ade ọba amọ awọn ko tii ri ọpa aṣẹ ti wọn gbe lọ.

"Ni ọjọ kejila oṣu Kẹwaa ọdun 2023 yii ni a gbọ lati aafin ọba Ogunmakin pe Ọgbẹni Amusa Kazeem, Ọgbẹni Oke Oladipupo ati Ọgbẹni Johnson Oluwole gbimọ pọ lati ji ade àti ọpa aṣẹ kabiyesi to waja.

Ni bii ago meji oru ni a gbọ pe awọn afurasi naa wọ ibi ti wọn ko ade ati ọpa aṣẹ naa pamọ sí.

Niṣe l'awọn mẹtẹẹta lọ mu kọkọrọ ibi ti wọn ko ade ati ọpa aṣẹ pamọ sí ti wọn si jigbe lọ.

Kete ti awa ọlọpaa ti gbọ ọrọ yii ni a bẹrẹ iṣẹ ti a sí ri ade gba pada nile Ọgbẹni Kazeem Amusan.

A sí n ṣe akitiyan ati iwadii lori ati ṣawari ọpa aṣẹ naa," agbẹnusọ ọlọpaa Ogun lo sọ bẹẹ.

O ni kọmiṣọnna ọlọpaa gan an, Ọgbẹni Abiodun Alamutu parọwa s'awọn eeyan to ba kofiri ọpa aṣẹ ti wọn n wa pe ki wọn kan si ileeṣẹ ọlọpaa.