Ìyàwó tó dá òróró gbóná sórí ọkọ rẹ̀ sàlàyé ìdí tó fí ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú akọ̀ròyìn

Oríṣun àwòrán, Rivers Police Command
Obinrin kan ni ipinle Rivers, ti o fi ororo gbigbona wẹ ọkọ rẹ ni Okehini ijọba ibilẹ Etche ti ṣalaye ohun ti o ri lọbẹ ti o fi waaru ọwọ.
Arabinrin naa Favour Nweke ti mu ọpọ alaye bẹnu idi to fi da ororo gbona si ara ọkọ rẹ arakunrin Ekelediri Nwokekoro nigba tawọn ọlọpaa lagbegbe naa ṣe afihan rẹ fawọn akọroyin.
Lati igba ti iroyin lu sita pe o da ororo sọkọ rẹ lara ni arabirin yi ti na papa bora tawọn eeyan ko si mọ ibi to wa titi di igba tawọn ọlọpaa ati fijilante ṣawari rẹ nibi to sa si.
Nweke ti awọn ọlọpaa ṣafihan rẹ pẹlu awọn lọwọ fi ẹkun bẹnu to si ni oun ko loke miran ju ọjọ oun lọ.
O sọ pe, “ Ọkọ mi a maa yọ jade, ni nnkan bi aago meji oru ti yoo si pada wọle ni afẹmọju. Nigba miiran yoo lọ, yoo si lo ọjọ meji tabi mẹta ki o to pada wa sile ti mo si maa n beere lọwọ rẹ ibi ti o lọ''
O tẹsiwaju pe “Nitorina ọrẹ rẹ pe mi o beere boya mo ti gbọ ohun ti o sẹlẹ, Mo si dahun pe ‘Kini yẹn?’
O ni ọrẹ oun sọ pe ọkọ oun ati awọn eniyan kan kopa ninu iṣe bonkẹlẹ kan.
O sọ pe wọn pe ẹnikan lati ilu Abuja pe eniyan yẹ ki o wa maa ṣiṣẹ ni Etche, ati pe wọn ni adehun lati fun ẹni naa ni isẹ nigbati eni ọhun ba de, wọn gbero lati gba N20 milionu lọwọ onitọun.
“Mo sọ pe ko sọ fun mi, mo n gbọ eleyi fun igba akọkọ ni,.Mo sọ pe ‘Abajọ ti ọkunrin yii fi n wu awọn iwa ajeji, oun gbero lori bi o ṣe le rin irin-ajo ati lọ si orilẹ-ede Afirika kan. Nitorinaa ni mo fi se ohun ti mo se.'
Mo koju ọkọ mi pẹlu nkan ti mo gbọ ṣugbọn ko jẹwọ
Arabinrin Nweke loun ṣe suuru titi ti ọkọ oun fi de toun si gbe ọrọ naa si niwaju.
Kaka ki baale rẹ jẹwọ, o ni niṣe lo kọ lati jẹwọ.
O loun tẹsiwaju lati beere pato nkan ti ọkọ oun fi owo tiẹ ṣe nitori ''mo gbọ pe awọn iyoku ti wọn jijọ pin owo ra ilẹ ninu owo ti wọn''
“ Bi a ṣe n fa ọran yẹn ni owurọ yẹn, o lu mi, Mo sare wọ ile idana ti mo si gbe ororo ti o wa lori ina ti mo sii daa si lara. Bi ọro naa ṣe ṣẹlẹ ni yẹn.”
“ Inu mi ko dun rara ti mo ba mọ pe nkan yii yoo ri bayi ni mi o ba ti ma ṣe.
O ni oun ko ba kan kuro ninu ile amọ ibinu ko jẹ.
O wa tọrọ aforijin lọwọ ọmọ Naijiria.
Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Rivers Edeka Nwonyi ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe Nweke yoo jẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.












