Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nọ́ọ̀sì ni ọmọ mi, abẹ́rẹ́ Paracetamol, Tetanus àti Antibiotics ló fún Mohbad - Ìyá nọ́ọ̀sì Feyisayo ké gbàjarè

Iya Noosi ati Mohbad

Oríṣun àwòrán, LEGIT.NG

Ìyá nọ́ọ̀sì tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó gún gbajúgbajà olórin tàkasúfèé nnì, Ilerioluwa Oladimeji Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad tó jáde láyé nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023, Feyisayo Ogedengbe ti jiyàn pé ọmọ òun lọ́wọ́ nínú ikú olórin náà.

Ìyá Feyisayo ní ọmọ òun kò mọwọ́ mẹsẹ̀ lórí ikú Mohbad àti pé kí àwọn ènìyàn yé pé ọmọ òun ní nọ́ọ̀sì ayédèrú.

Ó ní nọ́ọ̀sì tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ ni ọmọ òun àti pé ọdún mẹ́ta ló fi kọ́ṣẹ́ nọ́ọ̀sì ní ilé ìwòsàn aládàni kan ní ìpínlẹ̀ Ogun tó sì tún ṣiṣẹ́ fún ọdún kan ni ilé ìwòsàn náà kó tó kúrò níbẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé láti ìgbà tí ọmọ òun sì ti ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ kò fi ìgbà kankan ṣe àṣemáṣe nídìí iṣẹ́ náà kí wàhálà eléyìí tó wáyé.

Feyisayo kò mọ Mohbad rí tẹ́lẹ̀, ọ̀rẹ́ Mohbad ló máa ń tọ́jú

Ìyá Feyisayo tẹ̀síwájú pé ọmọ òun kò mọ Mohbad rí ṣáájú ìgbà tó lọ fun ní abẹ́rẹ́ náà.

Nínú fídíò kan tó wà lórí ayélujára ni ìyá náà ti ṣàlàyé pé ọ̀rẹ́ Mohbad kan tí wọ́n ń pè ní Spending ni Feyisayo máa ń tọ́jú tẹ́lẹ̀ àti pé òun ló pe Feyisayo láti wá tọ́jú Mohbad.

Ó ní ọmọ òun sọ fún òun pé láti ọdún 2019 ni òun ti mọ Spending tí òun sì máa ń tọ́jú rẹ̀ kó tó pe òun láti wá bá òun tọ́jú ọ̀rẹ́ òun tí ọwọ́ ń dùn.

"Cotonou ni Feyisayo ti ń bọ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n pè é láti wá tọ́jú Mohbad, ó sọ fún Spending pé kó fi àwòrán ọwọ́ tó ń dun Mohbad ránṣẹ́ sí òun tó sì ṣe bẹ́ẹ̀."

"Feyisayo ní abẹ́rẹ́ Tetanus, Paracetamol àti Anti-biotics ni òun fún Mohbad, pé àwọn abẹ́rẹ́ náà kìí ṣe nǹkan tó lè dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Ó fi kun pé ìyàwó Mohbad, àbúrò rẹ̀ àtàwọn èèyàn míì ló wà níbẹ̀ nígbà tí Feyisayo lọ ṣe ìtọ́jú Mohbad, pé kìí ṣe ohun tó wáyé ní bòńkẹ́lẹ́ rárá.

Fúnra mi ni mo mú Feyisayo lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí Mohbad kú

Ìyá náà ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun pé wọ́n fẹ́ di ẹrù ikú Mohbad lé ọmọ òun lórí, pé ọmọ òun kọ́ ni ó pa Mohbad àti pé àwọn abẹ́rẹ́ tó fun kìí ṣe ohun tó lè pa Mohbad rárá.

Ó ní òun àti Feyisayo ni àwọn jọ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ kí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí ìwádìí wọn àmọ́ ó ya òun lẹ́nu pé wọn kò fi ọmọ òun sílẹ̀ láti ìgbà náà.

Ó fi kun pé nǹkan tí àwọn ọlọ́pàá so fún àwọn ni pé tí èsì àyẹ̀wò ìwádìí òkú Mohbad tí wọ́n ṣe bá jáde ni wọ́n máa fi ọmọ òun sílẹ̀ àmọ́ ìwádìí náà ti ń pẹ́ ju bí òun ṣe lérò lọ.

Ó ní ó ti lé ní ogúnjọ́ tí ọmọ òun ti wá ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n sì fẹ́ di ẹrù ikú náà lé ọmọ òun lórí.

Bákan náà ló ké gbàjarè sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti ran òun lọ́wọ́ kí wọ́n má jẹ̀ ẹ́ kí ọmọ òun jẹ ìyà tí kò mọ ìdí rẹ̀.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post