Lẹ́yìn ọdún kan tí a pàdánù Ifeanyi, Ọlọ́run fi ìbejì ta ìdílé mi lọ́rẹ - Davido

Oríṣun àwòrán, @davido/INSTAGRAM
Gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, David Adeleke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Davido ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìyàwó òun ti bí ìbejì.
Davido fìdí ìròyìn náà múlẹ̀ nígbà tó ń kópa níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Láti bí ọjọ́ mélòó kan ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé Davido àti ìyàwó Chioma bí ìbejì ní Amẹ́ríkà àmọ́ tí kò ṣo ohunkóhun nípa rẹ̀.
Nígbà tí gbajúmọ̀ lágbo eré ìdárayá mìíràn tún ki lórí ayélujára fún ayọ̀ oríire náà, Davido faraya pé kò yẹ kí ònítọ́hùn gbé ìròyìn náà sórí ayélujára.
Àmọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ọ̀hún, ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún pé nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2022 ni òun àti ìyàwó òun, Chioma pàdánù ọmọ àwọn ìyẹn Ifeanyi, tí Ọlọ́run sì tún fi ìbejì kẹ́ àwọn ní ọdún kan lẹ́yìn rẹ̀.
Ó ní níṣe ni inú àwọn kún tí ayọ̀ àwọn sì pọ̀ nígbà tí àwọn dókítà sọ fún àwọn pé ìbejì ní ìyàwó òun máa bí.
Ó fi kun pé kìí ṣe ohun tó rọrùn fún ìdílé àwọn nígbà tí àwọn pàdánù ọmọ náà àti pé ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ènìyàn tí àwọn ní lọ́dọ̀ ni àwọn fi tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò ayé àwọn.
“Ọ̀pọ̀ àwọn tí nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí ni wọn kìí lè gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́ nítorí ìjákulẹ̀ tó máa ń wá pẹ̀lú rẹ̀.”
Davido tún yẹra lórí ìròyìn ìbejì ìyàwó rẹ̀, Ó ní ‘ẹ yé gbé fọ́tò àtijọ́ kiri nípa mi’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajugbaja olorin taka-sufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ti parọwa si awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye lati dẹkun lilo fọto atijọ fi ki oun lori iroyin pe iyawo rẹ ṣẹṣẹ bimọ.
Davido sọrọ yii loju opo ayelujara ti X ti ọpọ mọ si Twitter tẹlẹ.
O ni pe fọto atijọ ni awọn kan n gbe kaakiri nipa oun wi pe iyawo oun, Chioma ti bi ibeji siluu Amẹrika.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lati bi ọjọ diẹ sẹyin ni awọn ololufẹ gbajumọ akọrin agbaye naa ti bẹrẹ si ni gbe fọto rẹ kaakiri wi pe iyawo rẹ, Chioma ti bi ibeji si orilẹede Amẹrika.
Ọpọ awọn eeyan lo ti n ki Davido ati iyawo rẹ, Chioma ku ewu ọmọ; ti eekan lagbo amuludun pẹlu ko gbẹyin.
Ṣugbọn Davido ninu ọrọ to kọ lo ti sọ pe “Ẹ dẹkun pinpin awọn fọto atijọ kaakiri, ẹ ṣeun ❤️”
Bi Davido ṣe gbe ọrọ yii jade l’awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi, ti wọn si n beere lọwọ rẹ wi pe ṣe lootọ ni Chioma bimọ abi ko bimọ.
Wọn ni ki Davido f’idi rẹ mulẹ fun wọn boya otitọ ni iroyin ibeji ti wọn sọ pe Chioma bi, ko ma si jẹ pe ori fọto atijọ nikan ni yoo sọrọ le lori.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn ololufẹ to le ni miliọnu kan ni wọn ti wo ohun ti Davido kọ naa, to si jẹ pe awọn to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan ni wọn sọrọ sabẹ rẹ, leyi ti awọn eeyan n sọ pe ko tan imọlẹ sọrọ ibeji ti wọn sọ pe iyawo rẹ, Chioma bi.
Ni ibẹrẹ ọdun yii ni Davido ninu ifọrọwerọ to ṣe lo ti f’idi rẹ mulẹ pe oun ti ṣe igbeyawo.
Davido ati Chioma ni wọn ṣe igbeyawo lẹyin ti wọn padanu ọmọ wọn, Ifeanyi ninu oṣu kẹwaa, ọdun to kọja.














