Ìjọba àpapọ̀ tún fẹ́ ya $1.5bn láti ọwọ́ báńkì àgbáyé

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/Facebook

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria tun ti fẹ ya biliọnu kan aabọ owo dọla $1.5bn lati ọwọ banki agbaye.

Minisita eto inawo, Wale Edun ṣalaye pe ijọba ti n ba banki agbaye sọrọ lori ati ya owo fun afikun eto iṣuna.

Minisita eto inawo sọrọ yii nibi ipade banki agbaye ati ajọ IMF to n lọ lọwọ niluu Marrakech lorilẹede Morocco.

Lẹyin bi oṣu meloo sẹyin ni ijọba kede pe oun ko ni saaba yawo ṣe ijọba wi pe oun yoo wa owo lati ṣe ijọba labẹle.

Edun ni owo $1.5bn ti ijọba fẹ ya ko ni ni ele lori.

Ni bayii, gbese tiriliọnu aadọrun din mẹta naira, N87tn eleyii ti IMF sọ pe ko pọju fun Naijiria lati san.

Minisita ni ijọba yoo lo owo yii fun idagbasoke eleyii ti yoo sẹnu ‘re fawọn ọmọ Naijiria.

Ọgbẹni Edun ṣalaye pe banki agbaye maa n ya wọn orilẹede to ko ba ri ọwọ họri ni iru owo yii.

Minisita eto inawo fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe gbogbo eto ti ijọba apapọ n ṣe ni yoo kẹsẹ jari.