Ẹ simi ariwo, Tinubu kọ́ ló jẹ́ kí Sunday Igboho gb'òmìnira ní àhámọ́ - Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/INSTAGRAM
Olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oódua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti ṣalaye pe aarẹ Bọla Tinubu kọ lo ṣe agbatẹru bi ajijagbara nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ṣe gba ominira kuro ni ahamọ lorilẹ ede Benin.
Ṣaaju ni Igboho ṣe fidio kan ninu eyi ti o ti ki awọn alẹnulọrọ kan nilẹ Yoruba fún akitiyan ati aduroti wọn lẹyin ti ijọba orilẹ ede Benin fun ni ominira lẹyìn ọdun mẹjọ to ti wa lahamọọ.
Amọ, Ọjọgbọn Akintoye ni lati kede pe Tinubu kọ lo jẹ ki Igboho gba ominira lẹyin ti ajijagbara kan nilẹ Igbo sọ pe o yẹ kí Tinubu paṣẹ ominira olórí ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu naa bi o ti ṣagbatẹru ominira Igboho ni ahamọ lorilẹ ede Benin.
Olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oódua fi ọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sita eleyii ti agbẹnusọ rẹ, Gani Alagbala buwọlu.
Ọjọgbọn Akintoye sọ pe "a dúpẹ lọwọ Ọlọrun at'awọn olori wa nilẹ Yoruba to fi mọ awọn ọrẹ nile ati loke òkun okun fun iranlọwọ ati aduroti wọn lori ọrọ yii.
Ogun to le ni, amọ a dúpẹ lọwọ Ọlọrun pe Igboho pada gba ominira.
A tun fi asiko sọ pe ko sí ọwọ oloṣelu kankan tabi ijọba orilẹ ede Naijiria ninu ati gba ominira Sunday Igboho.
A dúpẹ lọwọ ijọba orilẹ ede Benin fun bi wọn ti gbá idajọ ododo laaye lẹyin o rẹyìn.
Bakan naa ni a gbadura pe Maazi Kanu maa to gb'ominira lahamọọ to wa ni Naijiria.''















