Ẹ fọkàn balẹ̀,ìpínlẹ̀ Oyo ṣetán láti sọ ọdún ìbejì Igboora dì ìlúmọ̀ọ́ká-Seyi Makinde

Aworan Gomina Seyi Makinde ati awọn to kopa ninu ọdun ibeji Igboora

Gomina ipinlẹ Oyo ti ṣeleri lati jẹ ki ayẹyẹ ọdun ibeji to maa n waye ni ilu Igboora di ohun ti gbogbo aye yoo maa gboṣuba kare fun.

O fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n ba araalu sọrọ nibi ayẹyẹ tọdun yi lọjọ Abamẹta.

Tilu tifọn ti ninu orisi aṣọ ni awọn ibeji, ibẹta, awọn obi, aṣoju ijọba,ọba ilu ati awọn ijoye, araalu pẹlufi peju pesẹ siluu Igboọra nipinlẹ Ọyọ lọjọ Abamẹta fun ayẹyẹ ọdun awọn ibeji lagbaye tọdun yii.

Ayẹyẹ naa ṣe koongẹ ọjọ ti ajọ agbaye n ṣe ayajọ ọjọ ibi awọn ibeji lagbaye.

Awọn to si ṣagbatẹru ayẹyẹ tọdun yi ni ẹka ile iṣẹ iroyin, aṣa ati irinajo igbafẹ nipinlẹ Ọyọ, ijọba ibilẹ arin gbungbun Ibarapa, ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilu Igboora ati ajọ to n risi idagbasoke awọn ibeji l'agbaye.

Lara awọn to ba wọn pejọ pọ sibi ayẹyẹ naa ni Gomina Ipinlẹ Oyo Onimo ẹrọ Seyi Makinde, igbakeji Gomina Ipinlee Ọyọ Amofin Bayo Lawal alakoso fun iroyin, asa ati irinajo igbafẹ ipinlẹ Ọyọ, Wasiu Olatunbosun, alaga ijọba ibilẹ Ibarapa, Họnọrebu Adedoyin Adeoye Habib ati bẹẹbẹẹ lọ.

Iwadii awọn akọṣẹmọṣẹ nipa onka awọn eeyan ilu lagbaye fidirẹ mulẹ wi pe ilu Igboora lo ni onka awọn ibeji to pọ julọ l'agbaye, pẹlu alaye wipe okere tan, ibeji mejidinlọgọjọ lo ma a n wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹrun kan ti wọn ba bi nilu Igbo-Ọra.

Eleyi si tayọ ibeji marun un pere to ma a n wa ninu awọn ọmọ ẹgbẹrun kan ti wọn ba bi ni gbogbo ilẹ Yuroopu.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọlọpọ awọn ara ilu Igboora gbagbọ wipe Amala ati ọbe Ilasa ti awọn eeyan ilu naa kundun lo n ṣokunfa ibeji ati ọmọ to ju meji lọ, bẹẹ si ni awọn ẹlomii ri iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun ti o ti ọwọ Ọlọrun wa.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina ipinle Oyo, onimọ ẹrọ Seyi Makinde ṣeleri wi pe oun yoo sa gbogbo agbára ohun lati ri wi pe ẹka to n ri si ẹtọ igbafẹ ipinlẹ Oyo gun oke agba sii.

Makinde nii ''ẹka asa ati igbafẹ ipinlẹ Oyo le dagba ti yoo si mu ki ọrọ ajẹ ipinlẹ yii goke agba sii.''

O ṣeleri lati da ile redio kan silẹ ni agbegbe Ibarapa ki awọn ara agbegbe naa le ba mọ si nipa awọn igbiyanju ijọba oun.

Ninu ọrọ kọmisona fun Asa ati eka igbafẹ ipinlẹ Oyo Wasiu Olatunbosun o ni ''o le ni milliọnu marun-un eeyan to n ṣe abẹwo si ipinlẹ Oyo lati wa gbafe ati lati mo si nipa awọn eto to nise pẹlu irinajo igbafẹ lododun.''

Wasiu ni ijọba ipinlẹ Oyo yoo gbiyanju lati sọ ayẹyẹ ayajọ ọdun awọn ibeji l'agbaye di oun ti gbogbo orilẹ-ede Naijiria yoo tẹwọ gba.

Aworan ikinikaabọ si ayẹyẹ ọdun ibeji ni Igbo Ora