Wọ́n ká orí èèyàn mọ́ Pásítọ̀ àti àwọn mẹ́ta míì lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Pasitọ ìjọ Chrust Liberty Evangelism ni agbegbe Iyana Iyesi niluu Ota, ipinlẹ Ogun, Oyenekan Oluwawaseyi pẹlu eeyan mẹta míì ni ileeṣẹ ọlọpaa ka orí eeyan mọ wọn lọwọ.
Iṣẹlẹ ohun lo waye lọjọ Aiku ni agbegbe Saje niluu Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun.
Oluwaseyi ati awọn mẹta mii, Ibrahim Agbowewe, ẹni ọgbọn ọdun, Suleiman Ogunbummi, ẹni ogoji ọdun ati Gafari Akinsanya, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta lo ti wa ni ahamọ Ileeṣẹ Ọlọpaa.
Iwadii ileeṣẹ Ọlọpaa safihan àwọn afurasi ni wọn yabo agbegbe naa ti wọn si palẹmọ awọn afurasi.
Àwọn nnkan mii tí wọn ka mọ awọn afurasi naa lọwọ ni igba ńlá,ọkọ ayokẹlẹ ati agbo , ti wọn si ti wa ni ahamọ
Agbenusọ ile ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Omolola Odutola, ẹni to fidi ileeṣẹ naa mulẹ, to si ni awọn afurasi mẹrin naa ti jewọ ohun ti wọn ṣe.
“Ọwọ ti tẹ awọn afurasi mẹrin naa. Wọn tí jewọ pe awọn fẹ lo orí eeyan lati se Ogun owo..
"Iwadii n lọ lọwọ lọwọ bayii lori awọn afurasi naa.''















