Tí a kò bá kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn Ilé-Ifẹ̀, a ò ní jámọ́ nǹkan kan - Ọọ̀ni

Oríṣun àwòrán, Ooni Ife Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi - Ojaja II
Ọọni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja II, sọ pe Ile-Ife wa ni arin awọn ilu ti ko yẹ ki awọn Yoruba maa mo itan rẹ bo ṣe le wu ko kere mọ yala wọn wa ni ile tabi lẹyin odi.
Oba Ogunwusi fidi ọrọ yi mulẹ nibi apero kan ti wọn pe akori rẹ ni ''ibaṣepọ to wa laarin aṣa ati aye ode oni''
Ile Ife ni apero naa ti waye lọjọ Abamẹta.
Ọjaja II sọ pe bi awọn Yoruba ko ba gbiyanju lati sọ itan araawọn,''awọn ajoji ni wọn yoo kan maa reti lati sọ nipa itan wọn''
Lẹnu ọjọ mẹta yi, ọrọ aṣa ati itan Yoruba jẹ nkan tawọn eekan to fi mọ awọn elere fiimu n ṣe igbelarugẹ rẹ ninu ere wọn.
Ooni pe gbogbo awọn ọmọ ilẹ Yoruba lati rii daju pe wọn ṣe atilẹyin fun awọn oonkọtan lati ṣe iwadi to gunrege lori itan Ife ki wọn si gbe gbogbo awọn igbese to yẹ ki wọn gbẹ ninu iwadii wọn.
Bakan naa, Ọjọgbọn kan ni ẹkaa ti wọn ti n ṣe akojọpọ itan ni fasiti Ibadan,UI, Ọjọgbọn Olutayo Adesina, sọ pe aṣa ati iṣẹlẹ ode oni ko yẹ ki o maa ni ajọṣepọ pẹlu ara wọn.
Adesina sọ pe “ A ni ọpọlọpọ awọn ohun lati kọ ẹkọ itan nipa rẹ ti yoo pese iṣẹ lọpọ yanturu fun olugbe orilẹ-ede yi.''
O fi kun ọrọ rẹ pe lilo itan lọna to yẹ yoo fun awọn eeyan loye bi wọn ṣe le pa aṣa ati igbalode papọ fun ilọsiwaju Naijiria.
Bẹẹ naa lo ni “awọn ọba jẹ alakoso agbegbe wọn ati olutọju aṣa ati pe wọn mọ pe ọpọlọpọ awọn anfani lo wa lati inu ohun ti a ni.
“O yẹ ki a yago fun sisa kuro lorilẹ-ede Naijiria nitori pe kii ṣe awọn ohun alumọni nikan ni ani lorilẹ wa, ṣugbọn ọpọlọpọ awọn orisun aṣa to wa ni orilẹ-ede yi le mu idagbasoke ba awujọ wa, ”
O wa gba gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria niyanju lati ni ifọwọsowọpọ lati rii daju pe gbogbo ohun ti wọn ni labẹ iṣakoso wọn mu idagbasoku wọ ilẹ Yoruba ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ
Nigbati oun naa da si akori ọrọ yi, Ọjọgbọn Siyan Oyaweso dupẹ lọwọ awọn ti o wa ni ibi eto naa ti o si ṣọ pe eleyi ṣafihan bi awọn ọmọ Yoruba se mo asa ilẹ wa ni okunkundun.
Oyaweso dupẹ lọwọ awọn agba akikanju ti wọn ti sesẹ ribiribi lateyin wa.
O dupẹ lọwọ awọn bi Pa Eni Fasogbon ati Pa Micheal Fabunmi, laarin awọn miiran,fun ipa ti wọn ti kọ lori itan Ile-Ife.
Oyaweso bẹbẹ fun atilẹyin Ooni lati lọwọ ninu kikọ iwe itan ilẹ Yoruba lakoko Apejọ Kariaye ni ọdun 2023.
O gba Igbakeji-Yunifasiti ti Ile-ẹkọ giga Obafemi Awolowo (OAU), Ọjọgbọn Simeoni Bamire niyanju lori idasile Ẹka Archaeology lati mu ki iwadii lori itan Ile Ife tunbọ kun si.












