‘Ọ̀ọ̀nì kan ló gé ẹsẹ̀ mi já’

Àkọlé fídíò, ‘Ọ̀ọ̀nì kan ló gé ẹsẹ̀ mi já’
‘Ọ̀ọ̀nì kan ló gé ẹsẹ̀ mi já’
Arabinrin ti ọọni ge lẹsẹ jẹ

Bi ipade ọrọ ayika ṣe n lọ kaakiri agbaye, awọn agbegbe kan wa nilẹ Afrika to jẹ wi pe wọn n fi ori fa gbogbo wahala ọrọ ayika to n waye kaakiri.

Lara awọn agbegbe bẹẹ lawọn eeyan eti odo Baringo ni Kenya.

Awọn eeyan agbegbe naa ti gbe ijọba orilẹede ọun lọ si ile ẹjọ nitori ipa to lodi ti ayipada oju ọjọ ati ayika n ni lori aye wọn.

Wọn ni o ti mu ki omi odo naa tubọ kun si ni ilọpo ilọpo eleyi to ti ṣi ọpọ olugbe ibẹ kuro nibẹ

Aworan obinrin kan leti odo pẹlu ọọni ninu omi lọọkan.

Bakan naa ni wọn ni igbagbọ pe o ti tubọ mu ki iye bi iṣẹlẹ ijamba ikọlu awọn ọọni o tubọ pọ sii lagbegbe etido naa.

Wọn ni bi odo naa ṣe n kun sii lo n mu ki awọn ọọni inu rẹ lanfani ati tubọ sunmọ awọn olugbe ibẹ.