Ìrọ̀rùn dé! WHO buwọ́lu abẹ́rẹ́ àjẹsára tí yóò kojú àìsàn ibà asẹkú pa ọmọdé

Aworan oṣiṣẹ ilera

Oríṣun àwòrán, Oxford University

Ajọ to n mojuto ilera lagbaye WHO ti buwolu lilo abẹrẹ ajẹsara ẹlẹdinwo kan tó lè koju aisan iba jakejado agbaye.

Fásítì Oxford ni wọn tí peelo rẹ, òhun sí ní ẹlẹẹkeji iru rẹ ti wọn tí ṣe.

Iba jẹ àìsàn to n sekupa ọkẹ àìmọye ikoko ati ọmọde lagbaye.

Adehun ti wá láti pese mílíọ̀nù lọna ọgọrun abẹrẹ ajẹsara yii lọdọọdun.

O gba awọn onimọ ni nnkan tó lè ní ọgọrun ọdun lati lu aluyọ lori ipese abẹrẹ ti yóò kojú ibà yii.

Ẹfọn mùjẹ̀mùjẹ̀ lo jẹ atọna bi kòkòrò aifojuri to n fa iba ṣe n wọ agọ ara.

Awọn ọmọ ogun inu ẹjẹ kìí sábà rí kokoro aifojuri yii tori pe o maa n yi awọ padà ní gbogbo ìgba ni.

Eyi jẹ kó nira kí ará wa lè koju aisan naa ti o sí ṣoro lati pese abere ajẹsara tí yoo koju rẹ.

O ti n sunmọ ọdun meji báyìí tí abẹrẹ ajẹsara akọkọ táa mo sí RTS,S ti ileeṣẹ GSK peelo gba iyọnda lọdọ WHO.

Abẹrẹ ajẹsara meji to fara jọra

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus,adari agba WHO sọ pé asiko inu didun gidi gaa n ni ìṣẹlẹ yí.

O ní "mo máa n lala nípa ọjọ tí a o ní abẹrẹ ajẹsara tí yóò lapa aisan iba- báyìí meji labẹrẹ táa ní"

Ajọ WHO sọ pé isọwọ ṣiṣẹ awọn abẹrẹ mejeeji yi jọra ati pe kò sí ẹrí to fihan pe ọkàn dara jù ekeji lọ.

Amọ o ni iyatọ diẹ to wa ni ikapa lati pese abẹrẹ ti fasiti Oxford yi lọpọ yanturu.

Ileeṣẹ to n peelo abẹrẹ ajẹsara to tobi julọ lagbaye Serum Institute of India -ti wa ni ikalẹ lati pese ohun tó lè ní mílíọ̀nù ọgọrùn abẹrẹ yi lọdọọdun to sí ní ikapa kò ju bẹ lọ sí mílíọ̀nù lọna igba.

Ni bayii mílíọ̀nù méjìdínlógún abẹrẹ ajẹsara RTS,S to wa nilẹ.

Dọla meji sí dọla mẹrin (£1.65 to £3.30) níye owó abẹrẹ kọọkan ti eeyan kan yóò sí nilo abẹrẹ mẹrin.

Eyi ṣe deede idaji owó abẹrẹ RTS,S.

Ìmọ tekinoloji ti ko fi tara yatọ ni wọn fi ṣe awọn abẹrẹ mejeeji yi ti wọn a sí jọ máa koju iba ni àgbàlá idagbasoke kanna.

Ṣugbọn abẹrẹ tuntun yi rọrun lati peelo ti kò sí nilo ko pọ kò tó lè ṣìṣe lara.

Ni 2021 iye àwọn tó ní iba lagbaye jẹ mílíọ̀nù 247.

619,000 lo ba aisan yi lọ ti ọpọ ninu wọn sì jẹ ọmọde ti ọjọ ori wọn kò tó ọdún marun ùn.

O le ní ìdá 95% aisan iba ti o jẹ pé ilẹ Afrika ni wọn tí n rí.

Ikapa lati doola ẹmi

Dokita Matshidiso Moeti, adari àjọ WHO ni agbegbe Africa sọ pe "abẹrẹ tuntun yi ni ikapa lati yanju ìnira Ipese abẹrẹ yi fawọn to nilo rẹ"

O ní bi wọn ba peelo awọn abẹrẹ mejeeji yi ti sì kaari wọn yóò ṣe iranwọ nípa kikojuaisan iba ati didoola àìmọye ẹmi awọn ọmọde lagbaye.