Stephenie Rodriguez yóò padà wá sí Naijiria lẹ́yìn tó pàdánù ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèjì lọ́wọ́ àìsàn ibà

Oríṣun àwòrán, Stephenie Rodriguez
Itan arabinrin ọmọ ilẹ Australia, Stephenie Rodriguez, ti wọn ge ẹsẹ rẹ mejeji leyin to dubulẹ aisan iba ni Naijiria ti n fa ori ayelujara ya.
Stephenie sọ pe itan igbesi aye oun yipada lẹyin ti oun kopa ninu ipade apero kan, Hive Africa Global Leadership Program, niluu EKo lọdun 2019.
Nigba ti BBC kan si arabinrin naa, o ṣalaye pe e to mẹta ọtọtọ ni oun wa ṣe ni Naijiria, lara rẹ ni Hive Africa Global Leadership Program, nibi ti oun ti ba awọn eeyan sọrọ.
Lẹyin to sọrọ tan ni wọn ni wọn ni ko lọ si iwaju gbọngan ti eto na ti waye lati ya fọto, eyii ti wọn ṣe fun nnkan bii wakati meji gbako.
O ni "Ibi ti a ti ya fọto naa sunmọ eti omi, awọn dokita mi si sọ fun mi pe o ṣeeṣe ko jẹ pe asiko ti a lọ ya fọto naa ni ẹfọn bu mi jẹ, iyẹn ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ si aago meje alẹ."
Ohun to ṣẹlẹ lẹyin ipade naa
Lẹyin oṣe meji to kuro ni Naijria ni Stephanie bẹrẹ si n ṣaisan.
Aisan naa bẹrẹ pẹlu bo ṣe daku rangbandan ni papakọ ofurufu ni Boston, nilẹ Amẹrika lasiko to fẹ wọ ọkọ ofurufu pada si orilẹ-ede rẹ ni Australia.

Oríṣun àwòrán, Stephenie Rodriguez
Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn gbe e lọ sile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun ti Harvard, nibi ti awọn dokita ti ni ko ṣe awọn ayẹwo kan lati mọ irufẹ kokoro to n ba finra.
"Nigba ti wọn ṣe awọn ayẹwo naa tan ni esi rẹ fi han pe aisan iba wa ninu ẹjẹ mi."
Bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ naa yi itna igbesi aye rẹ pada, obinrin ọhun ni amuwa Ọlọrun ni.
Stephanie sọ pe "Iṣẹlẹ naa ko ṣeṣi waye nitori Ọlọruni ki ṣe aṣiṣe."
"Iṣẹ ti ̣Ọlọrun ran ẹfọn to jẹ mi lo wa ṣe."
Aisan cerebral malaria
Gẹgẹ bii nnkan ti awọn eleto ilera sọ, aisan iba ti wọn n pe ni "cerebral malaria" lo ba Stephanie finra.
O jẹ ọkan lara awọn ẹka aisan iba to buru julọ.
Lara awọn apẹrẹ aisan naa ni pe o le mu ki eeyan daku, o si maa n mu ki awọn ẹya inu ara kan, bii ifun, ẹdọforo, ati bẹẹ bẹẹ lọ kọṣẹ.
Ti aisan yii ba ti wọnu ara tan, o le ṣakoba fun ọpọlọ, ti yoo si mu ki eeyan maa gbagbe nnkan, nigba mii ẹwẹ irufẹ ẹni ti aisan naa ba kọlu ko ni le sọrọ daadaa.
Wayio, Stephanie ti sọ pe oun ko kabamọ pe wọn ge ẹsẹ ounn mejeji nitori aisan naa.

Oríṣun àwòrán, Stephenie Rodriguez
Idi ti wọn fi ge ̣ẹsẹ Stephaniue mejeji
Gẹgẹ bii ohun ti awọn dokita sọ nile iwosan Harvard, kokoro iba naa ti gba ida mẹjọ ẹjẹ to wa lara obinrin ọhun.
Wọn tun sọ pe aisan naa ti wọ inu ifun ati kindinrin rẹ lọ, eyii to mu ko daku ni papakọ ofurufu Boston.
Lẹyin awọn oniruru ayẹwo ti wọn ṣe, wọn ni lara awọn nnkan ti wọn yoo ṣe ni ki wọn ge ẹsẹ rẹ mejeji lati le gba ẹmi rẹ la.
Ṣugbọn Stephanie ko jẹ ki iṣẹlẹ naa da omi tutu si lọkan, koda, o ti n mura lati tun tẹkọleti wa si Naijiria lọdun 2022.

















