Baba Ijesha: Ilẹẹjọ́ fagilé ẹ̀bẹ̀ Baba Ijesha tó ní pẹ̀lú ipá ni òun fi kọ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá

Princess ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Princess Comedian, Baba Ijesha

Adajọ ileẹjo giga to wa ni Ikeja to n risi ọrọ ifipabinilopọ, Oluwatoyin Taiwo ti ko ọrọ Olanrewaju James ti ọpọ si Baba Ijesha danu pé òun kọ ni oun kọ gbogbo akọsilẹ ti ọlọpaa beere fun lọjọ ti wọn mu u.Adajọ Taiwo ni ẹ̀rí náà ko to nipa pe wọn na an àti pe ti wọn si fi tipatipa ni ko kọ ọrọ akọsilẹ.Ní ìtẹ̀síwájú igbẹjọ Baba Ijesha lórí ẹsun biba ọmọde lopọ ti wọn fi kan an, afurasi naa tún ti yọjú sílé ẹjọ lónìí lẹ́yìn ti awọn agbẹjọro rẹ̀ pe fun ki adajọ wọgile ọrọ akọsilẹ Ijesha nibi ẹjọ to oṣu to lọ nitori inu ira lo ti kọ ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network
Àkọlé fídíò, Mariam Balogun kunlekunle to fi gboorọ jẹka laarin awọn akẹgbẹ rẹ

Awọn olupẹjọ tun mu ẹlẹri wọn to jẹ ọlọpaa Abigael Onome wa si ileẹjọ lónìí lati tun wa ro tẹnu rẹ̀ leyii ti ọkan lara awọn agbẹjọrọ Ijesha Kayode Olabiran tun fọrọ wa a lẹnu wo ti awon olupẹjọ si sọ pé ẹlẹri awọn to kẹhin naa ni ọlọpaa ọhun.Ẹwè, nibi ti ẹjọ de duro bayii awọn olupẹjọ ti fi ẹjọ rọ̀ lati ọdọ wọn.

Agbẹjọro Olabiran ṣalaye ileẹjọ pada gba oun ti Baba Ijesha kọ silẹ ni agọ ọlọpaa gẹgẹ ọkan lara awọn ẹri ipẹjọ.

O ni oun adajọ sọ pe ko si ẹri to daju to le fidi rẹ mulẹ pe wọn lu Baba Ijesha ṣaaju akoko to kọ ọrọ rẹ silẹ.

Olabiran ni adajọ tun sọ pe ọmọdebinrin ti wọn fẹsun kan Baba Ijesha pe o fipa ba lopọ gan an lo lu u.

Agbẹjọro Olabiran wa fikun ọrọ rẹ pe Baba Ijesha lo ku bayii lati maa mu ẹri ijẹjọ wa ti igbẹjọ ba tun gberasọ lọdun to n bọ.

Ileẹjọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu tó n bọ ọdun 2022.