World Malaria Day:Kí gaan láwọn nkán tó n fa àìsàn ibà?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ ariyanjiyan lo n lọ lori awọn nkan ti o ma n fa aisan iba si ara awọn eniyan, paapaa ni ilẹ adulawọ.
Bi awọn eeyan ko ba di ẹbi aisan naa ru wiwẹ ninu ojo,wọn a ni jijẹ agbado sisun a ma mu iba wa.
Amọ ki gaan lawọn ohun to jẹ ojulowo to n fa aisan iba?
Dokita onimọ ijinlẹ nipa aisan, Tunji Abolarin salaye fun BBC pe irọ ni wi pe ẹni ti ojo ba pa le e ni aisan iba, ati wi pe ẹrọ amuletutu kii pa ẹfọn.
Dokita Abolarin lasiko to n sọrọ ni efọn to ni iba lara nikan lo lee fa iba si ara eniyan, ati wi pe iru ẹjẹ ti eniyan ni lee jẹ ki iba tete wọ eniyan lara.

O fikun wi pe nitori otutu, ẹfọri ati ara riro wa lara awọn apẹrẹ to ma n fi aisan iba han lo jẹ ki awọn eniyan ti ojo ba pa, ti aisan iba si ti wa lara wọn sọ wi pe ojo ma n fa aisan iba.

Bakan naa ni dokita naa ni ti ayika ba tutu, o see se ki ẹfọn ma le e raye nibẹ ju igba ti ayika ba gbona, eleyii ti o ma n waye lọpọ igba ni ilẹ Afirika.









